Number Plate: Ìlànà FRSC rèé láti gba nọ́mbà àdáni fún ọkọ̀ rẹ

Awọn ẹṣọ oju popo

Oríṣun àwòrán, Twitter/FRSC

Àkọlé àwòrán, FRSC ní àwọn kò mọ̀ nípa nọ́mbà ọkọ̀'CHIP WHIP'

Wo ilana ti eeyan gbọdọ tẹle to ba fẹ gba nọmba adani si ọkọ rẹ gẹgẹ bi ajọ ẹṣhọ oju popo FRSC ṣe laa kalẹ:

Ṣe iforukọsilẹ ọkọ rẹ

Igbesẹ akọkọ ni pe eeyan gbọdọ ṣe iforukọ silẹ ọkọ loju opo ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC (http://www.nvisng.org).

Loju opo ayelujara yii ni eeyan yoo ti fọwọ si fọọmu kan lati fihan pe ẹni naa fẹ gba nọmba aladani si ọkọ rẹ.

Fi fọọmu ranṣẹ si ọfiisi iwe aṣẹ iwakọ

Igbesẹ to kan ni lati mu fọọmu ti eeyan ba ti fọwọ si lọ si ọfiisi ti ajọ FRSC ti maa n fawọn awakọ

Nibi ni ẹni to fẹ gba nọmba adani ti gbọdọ sọ iru nọmba to fẹ gba si ọkọ rẹ gan an ninu fọọmu ti yoo ṣọwọ si ọfiisi ti wọn ti n gba iwe aṣẹ ọkọ wiwa.

Agbeyẹwo fọọmu fun nọmba adani

Ni ipele yii ni awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo yoo ṣe ayẹwo fọọmu ti wọn fi ṣọwọ si wọn finifini.

Lẹyin ayẹwo yii ni wọn yoo fi nọmba ṣọwọ si awọn alaṣẹ fun iwadii siwaju si.

Sanwo fun iforukọsilẹ nọmba rẹ

Nibayii, o ni lati gba fọọmu miiran eleyi ti wa tun fọwọ si.

Lẹyin naa ni wa sanwo fun iforukọsilẹ nọmba ti o ba fẹ, bakan naa ni wa tun sanwo fun iwe aṣẹ ọkọ wiwa loju popo.

Dida fọọmu pada

Bi ipele yii ni wa ti da fọọmu ti o ti fọwọ si pada si ọfiisi ajọ FRSC to maa n fawọn awakọ nọmba.

O gbọdọ mu iwe to jẹ ẹri idaniloju pe o ti sanwo ni tootọọ pẹlu fọọmu ti o fọwọ si lọ si ọfiisi FRSC.

Gbigba nọmba aladani ọkọ rẹ

Lẹyin ti o ba ti tẹ le gbogbo igbesẹ yii ni ajọ ẹṣọ oju popo yoo fun ọ ni nọmba ọkọ rẹ.

Bakan naa ni wọn yoo fun ọ ni gbogbo iwe to ṣe pataki fun lati ni nipa nọmba aladini rẹ.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Chip Whip: A ò mọ̀ nípa àṣìkọ orúkọ nọ́mbà ọkọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Kano - FRSC

Ajọ ẹka oju popo, FRSC ti ni awọn ko mọ nkankan nipa aworan nọmba idanimọ ọkọ ‘CHIP WHIP’ ti awọn eniyan n tan kalẹ ka lori ẹro ayelujara ni opin ọsẹ.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu aworan naa lẹyin ti o jade lori ẹrọ ayelujara, pẹlu asisẹ aato ọrọ kikọ

Àkọlé fídíò, Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Alukoro Ajọ FRSC, Bisi Kazeem ninu atẹjade ti wọn fi lede ni awọn kii ba wọn jẹ eera ti ko lọmọ ninu, nitori naa kii se ọdọ awọn ni asemase naa ti wa.

Wọn fi kun un wi pe awọn ma n se idanimọ ọkọ lorilẹede Naijiria letoleto ni, ti kii si ni abawọn.

‘CHIP WHIP’

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán, FRSC ní àwọn kò mọ̀ nípa nọ́mbà ọkọ̀‘CHIP WHIP’

Bakan naa ni wọn fi kun un wi pe awọn ko nii nkankan se pẹlu nọmba ọkọ ti wọn ni o wa lati ipinlẹ Kano, ti o si seese ko jẹ ti adari Ile Igbimọ Asofin ipinlẹ naa.

Ajọ FRSC naa wa tẹnu mọ ọ wi pe awọn ti bẹrẹ iwadii ni ẹka ajọ naa to wa ni ipinlẹ naa lati mọ ibi ti nọmba ọkọ ọhun ti ṣẹ wa.

Àkọlé fídíò, Lagos King: Mátikú ọba tó lo lo ọdun mẹta lórí oyé latari rogbodiyan Eko