Boko Haram video torture: A ṣetán láti fìyà tó tọ́ jẹ ọmọ ogun ti adé ìwà ìbàjẹ́ fídíò náà bá ṣímọ́ lórí

omo ogun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ọmọ ogun ko ni fọwọ yẹpẹre mu awọn ọmọ ogun to ba n fipa mú awọn ara ilu ṣe nkan ko tọ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Laarin opin ọsẹ to kọja ni fidio kan jade lori ayelujara to ṣafihan awọn ọmọ ogun kan to huwa ti ko ba ilasilẹ iṣẹ awọn ọmọ ogun ilẹ.

Ilé iṣẹ ọmọ ogun ni àwọn ko ni fọwọ rá ọmọ ogun ti igba iwa idajọ lọwọ ara ẹni ba ṣi mọ lori rara.

Eyi jẹ esi lori fonran kan to n tan ka lori ayelujara bi àwọn ọmọ ogun kan se pa afurasi Boko haram ti wọn si sin in si sààre ti ko jinlẹ ni ipinlẹ Borno ni ariwa ila oorun Naijiria.

Ileeṣe ọmọ ogun ile fi atẹjade sita lori ipinnu wọn lẹyin ti wọn bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa ipá naa pe ko ba ofin awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria mu.

Ileesẹ ọmọ ogun ilẹ Naijiria ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ni kikun lori fidio naa ati awọn to wa ninbẹ nitori pe iwa ti wọn hu lodi si ileeṣẹ omo ogun o si tun tabuku wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Ogagun agba Sagir Musa to jẹ adele adari agbẹnusọ fun ileeṣẹ omo ogun ilẹ iwa ipé yii ṣe lodi si ofin Naijiria.

Àkọlé fídíò, Yollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo
Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Sagir ni ọpọ igba ni wọn ti kilọ fawọn ọmọ ogun lati maa ṣọra ṣe paapaa nigba ti inu ba n bi wọn tabi ti nkan ṣẹlẹ ki wọn ma baa tẹ oju ẹtọ ara ilu mọlẹ.

Ni ipari, o ni wọn ti mọ pe ijiya to tọ wa fun ẹnikẹni to ba huwa aitọ ninu awọn ọmọ ogun Naijiria.

Àkọlé fídíò, ''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'