Iléesẹ́ ológun Nàìjíríà bẹnu àtẹ́ lu ìwádìí Amnesty International

Awọn ọmọogun orilẹede Naijiria nipinlẹ Borno

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọogun ko sinmi fifigba gbaga pẹlu awọn janduku orisirisi ni Naijiria

Ileeṣẹ ologun orileede Naijiria ti tutọ soke foju gba lori abajade iwadi kan ti ajọ to n tọpinpin ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International,gbe jade nipa Naijiria.

Koda wọn pe fun titi fun titi oriko ajọ naa jakejado Naijiria.

Ipe yi ko ṣẹyin iwadi kan ti ajọ naa gbejade to ti sọ wi pe o le ni ẹgbẹrun mẹta eeyan ti wọn ti lugbadi iku latari aawọ laarin awọn agbe ati darandaran ni Naijiria.

Ileeṣẹ ologun ninu atẹjade kan lati ọdọ ọgagun Sani Usman to jẹ gabẹnusọ wọn ni niṣe ni ajọ naa n gbero lati tu Naijiria ka.

Àwọn èrò gbé pósí àwọn ti darandaran pa ní Benue

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Bíi ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ ènìyàn ni ó ti kú ní Benue láti 2013

Amọ ṣa, ajọ naa ni ko si ootọ ninu nnkan ti ileeṣẹ ologun sọ nipa awọn.

Ajọ naa ni ileese ologun ko sapa to lati daa aabo bo awọn eeyan ti wọn si kọ lati ṣe iwadi tabi mu awọn ti wọn fura si wi pe wọn n ṣe iku paniyan.

Ninu iwadi ti ajọ naa gbe jadẹ, wọn ni iwadi naa dalori ikọlu awọn agbe ati darandaran to waye lagbegbe ariwa ati gbungbun Naijiria laarin oṣu kini 2016 ati oṣu kẹwa ọdun 2018.

Awọn afunrasi ti ọwọ ba joko lori ilẹ niwaju ologun

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Ọpọ awọn afyrasi lọwọ tẹ ti aimọye si jajabọ mọ awọn alaṣẹ lọwọ

Wọn salaye pe lẹyin ifọrọwanilẹnuwo pẹlu eeyan to to igba tawọn ṣe, awọn ri wi pe idaji awọn iku naa waye ni ọdun yi nikan.

Gẹgẹ bi ohun ti ajọ naa sọ, wọn ni awọn ileto bi mẹrindinlọgọta lawọn de lawọn ilu bi Adamawa,Banue,Kaduna Taraba ati Zamfara lati fi idi ọrọ naa mulẹ.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ajọ Amnesty International ati ileeṣẹ ologun Naijiri ayoo ma gbena woju ara wọn.

Losu kọkanla ọdun yi, adele oludari ẹka iroyin ileeṣẹ́ ologun Naijiria,ọgagun John Agim so wi pe ajọ Amnesty International n gbe iroyin ayederu jade nipa lNaijiria lati le bẹnu atẹ lu.

Lai pe yi ni ileeṣẹ́ ologun fẹsun kan ajọ to n risi itọju ọmọde kaakiri agbaye Unicef pe wọn n ṣe iranwọ fun ikọ Boko Haram.

Iye igba ti awọn darandaran ti se ikọlu si Adamawa, Benue, Taraba, Ondo ati Kaduna

  • February 2013; Awọn Fulani pa ọgọọrọ eniyan ni Benue
  • May 7, 2013: Awọn 47 ni wọn yinbọn pa nigbati wọn n sinku awọn ọlọpaa meji ti awọn Fulani darandaran sekupa
  • Feb 20-21, 2014: Awọn Fulani darandaran pa eniyan 35, ọgọọrọ si di alainile gbe
  • March 6, 2014: Awọn Fulani darandaran pa eniyan 30 ni agbeegbe Kwande, Katsina
  • March 23, 2014: Eniyan 25 padanu ẹmi wọn nigba ti 50 si farapa nibi ikọlu awọn darandaran si agbeegbe Gbajimba,ni Benue
  • March 15, 2015: Wọn se ikọlu si agbeegbe Egba ni Agatu LGA to si le ni eniyan 90 pẹlu obinrin ati ọmọde ti ẹmi wọn lọ si.
  • April 27, 2015: Awọn eniyan 28 ku ni ikọlu si ijọba ibilẹ Guma ni Benue
  • Feb 21-24, 2016: O le ni eniyan 500 to ku, ti ọgọọrọ si di alainile gbe nibi ikọlu si agbeegbe ijọba ibilẹ Agatu ni Benue
  • January 24, 2017: Ko din ni eniyan 15 ti awọn Fulani darandaran ti gba ẹmi wọn ni ibi ikọlu awọn Fulani si agbeegbe naa.
  • December 31, 2017 si January 2, 2018: Awọn Fulani darandaran pa eniyan mẹtalelaadọrin ni Benue
  • January 10, 2018; Eniyan 55 lo padanu ẹmi wọn ni Taraba
  • Jan 14 2018; Eniyan 10 ni awọn Fulani darandaran pa ni ipinlẹ Kaduna
  • February 12, 2018; Afunrasi Fulani darandaran pa agbẹ kan nilu Ipao Ekiti
  • February 13, 2018; Awọn darandaran le awọn osisẹ ijọba kuro ni ile isẹ wọn ni Akure
  • March 6, 2018; Fulani darandaran pa eniyan 24 ni Benue
  • April 5, 2018; Awọn darandaran pa eniyan mẹrin ni Taraba
  • April 12, 2018; Eniyan marun gbẹ ẹmi mi ninu ikọlu awọn darandaran si Nasarawa
  • April 13, 2018; Oku mẹẹdọgbọn tun sun nibi isinku apapọ ni Ikọlu Plateau
  • April 15, 2018; Darandaran tun gbẹmi mẹẹdọgbọn ni Kogi
  • Èèyàn mẹ́wàá kú nínú ìkọ̀lù tuntun ni Benue 21 04 2018