Bobrisky sàlàyé ipò tó wà gẹ́gẹ́ bi ọkunrin tàbí obinrin

Oríṣun àwòrán, @bobrisky
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Naijíría ló maa n sọ ni ọ̀pọ̀ ìgbà pé àwọn ko mọ ibi ti Idris Olarewaju Okuneye tó si n láàrin àkọ tà bí àbo?
Ọ̀pọ̀ a máa pe ni ọkúnrin pẹ̀lú igbàgbọ́ pé o kan n fi ìmúra rẹ̀ ran ọ̀rọ̀ ajé rẹ̀ lọ́wọ́ lásan ní àti pé orúkọ rẹ̀ ọkùnrin ní.
Sùgbọ́n Idris Olarewaju okuneye tí gbogbvo ènìyàn mọ si Bobrisky ti jáde síta bayiìí láti sọ ipo to wà fún gbogbo ayé yálà obinrin ni o tàbi ọkunrin.
Lóri atéjiṣẹ Instagram rẹ̀ ni Bobrisky ti sàlàyé pé ìrìnajo oun láti yìí kuro ni ọkkunrin si obinrin to rẹwa, jẹ́ èyi to dun yùngbàyungba.
O ni bótilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà àwọn iṣẹ́ abẹ ti ouhn ṣe jẹ́ eyi to wọ́n gidigidi ni ti Miílíọnu naira, síbẹ̀ oun yọlẹ se lábẹlẹ nótori àwọn ọmọ Niajiria ti yoo ma bẹ́nu atẹ lu oun.
Bobrisky fi kun pé àwọn igbésẹ̀ iṣẹ́ abẹ náà ko tii tan, sùgbọn nígba ti yóò ba fi di ìwòyí amọdun, oun fẹ́ díje fun ètò obinrin to rẹ̀wa júlọ lágbàyé (Miss World 2020)








