SERAP ké sí ààrẹ Buhari lórí èròngbà àwọn NCC àti NIMC lórí ìforúkọsílẹ̀ NIN

Oríṣun àwòrán, @SERAPNigeria
Ajọ ajafẹtọmọniyan kan ni Naijiria SERAP, ti kesi aarẹ Buhari lati jawọ ninu eto iforukọsilẹ awọn ọmọ Naijiria nipa nọmba idanimọ NIN.
Ajọ naa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku ni ihalẹ ijọba lati wọgile simu kaadi awọn eeyan ti ko ba ni nọmba yi ku diẹ kaatọ.
Kolawole Oluwadare, oludari ajọ SERAP lo fi atẹjade yi sita.
- Báyìí ni Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ṣe wọ ṣọ́ọ̀ṣì fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bá bàbá rẹ̀ ṣe ìdúpẹ́ ìwúyè
- Wo eyi to súnmọ́ ọ nínú àwọn ibùdó 203 fún ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ
- Anthony Joshua gba nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN, àwọn ọmọ Nàìjíríà kan kérora lórí ètò náà
- Bóò bá ní nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN, à tí kọ ìdánwò rẹ yóò ṣòro
SERAP ni ki aarẹ Buhari "paṣẹ fun Minisita feto ibaraẹnisọrọ ati eto ọrọ aje ayelujara Isa Pantami ati ọga agba ileeṣẹ to n mojuto eto idanimọ ni Naijiria NIMC iyẹn Aliyu Abubakar lati jawọ ninu igbesẹ yi''
Alaye SERAP ni pe awọn ọmọ Naijiria ti fi iroyin nipa ara wọn silẹ lọna aimọye to fi mọ ti BVN,iwe aṣẹ iwakọ, iwe irina ilẹ okere ati kaadi idibo.
Lọsẹ to kọja yi ni ijọba apapọ Naijiria gbe gbedeke kalẹ pe ki gbogbo awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọgile siimu awọn alabara wọn ti ko ba ti ni nọmba idanimọ NIN.
Bẹẹ lo tun sọ fun awọn ileeṣẹ yi lati fi to awọn alabara wọn leti pe ki wọn pese nọmba idanimọ yi lati fi mu iroyin wọn pe perepere.
Bakan naa ni wọn ni ki wọn ma se ta simmu tuntun tabi forukọ awọn to ba fẹ ṣẹṣẹ gba siimu mii silẹ.
Kolawole Oluwadare oludari SERAP wa sọ pe "Ko si ijọba kankan to lẹtọ lati gba ẹtọ araalu lọwọ wọn labẹ pe o fẹ ki wọn forukọsilẹ gba nọmba idanimọ.Ti awọn alaṣẹ ba kọ ti wọn tẹsiwaju pẹlu igbesẹ yi,idunkoko mọ ara ilu yoo peleke si ni ti ajọ NIMC to yẹ ko ṣiṣẹ rẹ bi iṣẹ yoo si dabi ẹsin inu iwe lasan ti ko le ta putu.''
Wọn wa ṣe lalaye pe ''kaka ki ijọba maa mu awọn eeyan nipa tabi ki wọn maa dunkoko mọ awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ eyi ti yoo jẹ ki wọn wa ninu ewu COVID-19, ohun to tọ ni ki wọn jẹ ki NIMC ṣe isẹ rẹ bo ti ṣe wa ni ibamu pẹlu ofin to ṣe idasilẹ rẹ.''
SERAP kangun ọrọ rẹ pẹlu alaye pe ko si ohun to mumu laya ijọba debi pe ki wọn wa maa ni ki awọn eeyan maa ṣa kijokijo nitori pe wọn fẹ gba nọmba idanimọ NIN yi.













