SERAP and Pension: Àjọ SERAP ké sí Buhari lórí èròngbà àwọn Gómìnà láti ná N17trillion nínú owó ìfẹ̀yìntì òṣìṣẹ́

Amin idanimọ ẹgbẹ SERAP

Oríṣun àwòrán, @SERAPNigeria

Ajọ ajafẹtọmọniyan kan ni Naijiria SERAP ti kesi aarẹ Buhari lati maa ṣe jẹ ki awọn Gomina ya triliọn mẹtadinlogun ninu owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ Naijiria.

Lọsẹ to kọja ni awọn Gomina kede ipinnu wọn lẹyin ti Gomina Nasir Elrufai jabọ ipade igbimọ ọrọ Aje lati ya ninu owo ifẹyinti oṣiṣẹ fun ipese awọn ohun amayedẹrun.

Àkọlé fídíò, India: Ẹ wo bí àwọn ènìyàn ṣe dóòlà èmí erin tó jálulẹ̀

Ninu lẹta kan ti igbakeji adari ajọ naa, Kolawole Oluwadare fi sita lọjọ Aiku o ni ''fifi aaye gba awọn Gomina lati ya ninu owo yi yoo ṣe akoba fawọn to ni owo naa''

O tẹsiwaju pe ''bi eeyan ba wo bi wọn ti ṣe n lu owo ifẹyinti ni ponpo ni Naijiria ati bawọn ipinlẹ kọọkan kii ṣe sootọ, ko yẹ ki wọn jẹ ki wọn ya ninu owo yi''

Ninu iwe yi ti wọn tun fi ṣọwọ si Minisita eto idajọ Naijiria SERAP ni ko ba ofin ilẹ Naijiria mu ki awọn Gomina maa foju si owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ lara ni gbogbo igba.

O ni inu awọn yoo dun ti ijọba Buhari baa le sọ ''igbesẹ to ti n gbe lati kọdi awọn Gomina lati ma ṣe ya ninu owo yi laarin ọjọ mẹrinla tawọn fi iwe ranṣẹ sii''

SERAP wa sọ pe bawọn ko ba gburo esi kankan lati ọdọ ijba laarin ọjọ mẹrinla awọn yoo gbe igbesẹ nile ẹjọ lati jẹ ki ijọba ṣe ohun tara ilu n fẹ lori ọrọ yi.

Aworan oṣiṣẹ fẹyinti Naijria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kí ló dé t'awọn Gómìnà Nàìjíríà fẹ̀ yá N17trillion nínú owó ìfẹ̀yìntì òṣìṣẹ́?

Ipinu awọn Gomina orileede Naijria labẹ aṣia ẹgbẹ Nigeria Governors Forum lati ya triliọnu mẹtadinlogun owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ ti n mu awuyewuye wa.

Ko si ṣẹyin bawọn Gomina ti ṣe sọ ipinu yi lẹyin ipade wọn to waye laipẹ yi pe awọn buwọlu aba meji ọkan ti wọn, ikeji ti banki apapọ CBN to fẹ ya ninu owo ifẹyinti oṣiṣẹ.

Ikede yi jẹ eyi ti ko dun mọ awọn oṣiṣẹ ninu ti wọn si ti tutọ soke foju gba a pe ki wọn maa dan wo rara.

Ninu ọrọ ti aṣoju awọn oṣiṣẹ fẹyinti sọ fun ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch, wọn ni awọn Gomina ti ko da ipin ti wọn ninu owo ifẹyinti oṣiṣẹ ko lẹtọ lati ya ninu rẹ.

''Awọn Gomina ko lẹtọ si owo yii. Kii ṣe owo wọn tori naa bawo ni wọn ṣe fẹ buwọlu aba lati ya owo ti wọn ko da sinu rẹ?''

Aworan NGF

Oríṣun àwòrán, NGFSecretariat

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn
Aworan NGF

Oríṣun àwòrán, NGFSecretariat

Bunmi Ogunkolade to jẹ olori ẹka iroyin ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹyinti Nigerian Union of Pensioners ṣalaye si pe ''pupọ awọn ijọba ipinlẹ ni ko da si owo ifẹyinti oṣiṣẹ'' .

Ogunkolade ṣalaye siwaju pe awọn ti ṣaaju kilọ fun ijọba apapọ lati ma ṣe tọwọ bọ owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ to si fi kun pe awọn ni yoo san owo yi pada tawọn Gomina ko ba ribi daa pada.

Labẹ ofin to de eto owo ifẹyinti ni Naijiria, awọn alakoso owo ifẹyinti yi ni wọn lẹtọ lati fi owo yi dokowo lọna ti yoo pawo wọle fawọn to ni.

Aworan oṣiṣẹ fẹyinti Naijria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ohun ta gbọ ni pe iye owo apapọ to wa ninu akoto owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ Naijira to triliọnu mọkanla Naira le diẹ bayi.

Ohun tawọn Gomina lawọn fẹ fi owo yi ṣe ni eto ipese ohun amayedẹrun fara ilu ti Gomina Kayode Fayemi to jẹ alaga ẹgbẹ awọn Gomina si ni awọn ti buwọlu aba owo yiya yi pẹlu eyi ti banki apapọ naa sọ pe awọn fẹ ya ninu owo ifẹyinti oṣiṣẹ.