US visa fee for Nigeria: Amẹrika ti yọ àfikún owó Físà kúro fún arìnrìnàjò Nàìjíríà

US visa fee for Nigeria: Amẹrika ti yọ àfikún owó Físà kúro fún arìnrìnàjò Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Buhari/twitter

Orílẹ̀-èdè Amẹrika ti yọ afikun owó fisa tó ṣe nítori èdè àìyedè tó wáye láàrìn òun àti ìjọba Nàìjíría kúrò láti ọjọ́ kẹta, oṣù kejìlá.

Nínú àtẹjáde ti kan ti ilé iṣẹ́ tó ri si ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ni Nàìjíríà fi síta pe ilẹ Amẹrika ti yọ owó gọbọi ti wọ́n fi le owo físà fáwọn Nàìjíríà kúrò.

Sáájú ni ìjọba Nàìjíríà ti fi owó kún owó físà fún àwọn ọmọ Amẹrika tó ba fẹ́ wa si Nàìjíríà, lẹ́yìn gbogbo àlàyé láàrin ìjọba Amẹrika àti Nàìjíríà ti kò kẹ́sẹ̀ jári.

Nínú oṣù kẹjọ, ọdún 2019 ní ààrẹ Donald Trump sọ owó físà ilẹ̀ Amerika di gọbọi láti fi gbẹ̀sàn lára Nàìjíríà fun owo gọbọi tti Nàìjíríà n gbà lọ́wọ́ ará Amẹrika to fẹ gba físà Nàìjíríà.

Wọ́n ní owọ ti ọmọ ilẹ̀ Amẹrika yóò fi gba físà wá si Nàìjíríà ti pọ̀ jú iyé ti Nàìjíríà fí n gbà físà lọ si ilẹ̀ Amẹrika lọ

Ilẹ̀ Amẹrika kọ̀wé ránṣẹ́ nínú oṣù kẹjọ pé gbogbo ẹni tó bá gba físà (irú èyí tí kì báà jẹ́) yóò san àádọ́fà dọ́là fún físà. (110).

Àkọlé fídíò, India: Ẹ wo bí àwọn ènìyàn ṣe dóòlà èmí erin tó jálulẹ̀

Ìjọba Nàìjíríà wá kéde ní ọjọ́ kejì pé àwọn ti mú àdínkù bá owó físà, sùgbọ́n Amẹrika ni àwọn ko ni àdínkù bá owó físà àfi ti wọ́n ba ṣe ni ìlana tó yẹ.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

Sùgbọ́n lẹ́yìn àtótónù àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì, Nàìjíríà mú àdínkù bá owó físà fún Amẹrika ti Amẹrika náà sì tì mú àdínkù bá tiwọn báyìí.

Ẹ̀wẹ̀, àtẹjáde láti ilé iṣẹ́ tó n ri si ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè kò sọ ní pàtó pé iye báyìí ni owó físà náà.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ