Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji

Oríṣun àwòrán, Naija info
Ẹbi ọkunrin ẹni ogoji ọdun, Enuduisu Odili to ku ninu ile itura, otẹẹli lẹyin to ni ajọsepọ pẹlu obinrin kan ti n bere fun iwadii to yanranti lati ọdọ ọlọpaa.
Iṣẹlẹ to waye lọjọbọ ni agbegbe Mile 2, Diobu, ni Port Harcourt, ipinlẹ Rivers to wa ni Guusu-guusu Naijiriani wọn sọ pé ọkunrin kan ku lẹyin to lọ gbadun ara rẹ ni otẹẹli kan.
Ko si ẹni to ye nkan ti o ṣẹlẹ ni pato ninu yara naa laarin ọkunrin to d'ologbe naa ati obinrin ọhun, sugbọn alẹ ọjọbọ naa lo gba yara naa ti wọn si ba oku rẹ ni owuro ọjọ Eti.
- Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ
- Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
- Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham
- Omotara kan ìdin nínú iyọ̀, àwọn ọmọ ilẹ̀ Faranse náà bínú síi nítorí alágbe tó fi ṣe yẹ̀yẹ́.
Aburo oloogbe oun Chukwuemeka Odili salaye fun oniroyin lorukọ gbogbo ẹbi ni ejo lọwọ ninu lori ọrọ naa.
Chukwuemeka ke pe kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers Joseph Mukan ati àti awọn ẹsọ alaabo to ku lati wadii nkan to fa iku ojiji ti ẹgbọn oun ku ati lati ri idajọ ododo.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers Nnamdi Omoni naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si fi kun pe obinrin ti o ba arakunrin naa ni ajọṣe pọ ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii
O fi kun pe wọn ti dari ẹjọ naa si ẹka iwadii iwa ọdaran ni ipinlẹ River fun iwadii to peye.
- Kí ló dé t'awọn Gómìnà Nàìjíríà fẹ̀ yá N17trillion nínú owó ìfẹ̀yìntì òṣìṣẹ́?
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Ṣé ẹ rántí àkọ́lé àwọn ìwé àkàgbádùn yìí?
- Wo bí ilé ìwòsàn LUTH ṣe ń gba owó ibùsùn lọ́wọ́ àwọn aláìsàn, tí àwọn míràn sì ń sun ìta














