Nigerian Recession: Ọ̀rọ̀ ajé Naijiria tó dẹnu kọlẹ̀ yóò kan gbogbo èèyàn

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2020, ni ijọba Naijiria kede pe eto ọrọ aje ti dẹnu kọlẹ.
Awọn onimọ si ti sọ asọtẹlẹ pe o ṣeeṣe ko jẹ ohun ni eyi ti yoo buru ju lẹyin ti oṣu Kẹjọ, ọdun 2016 lasiko ti owo epo rọbi ja walẹ kaakiri agbaye.
Gẹgẹ bi awọn onimọ nipa eto ọrọ aje ṣe sọ, ti ọrọ aje orilẹ-ede ba ti ja walẹ lere-lera laarin abala meji ọdun kan, o n tumọ si pe ifasẹyin ti de ba ọrọ aje irufẹ orilẹ-ede beẹ niyẹn.
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ tí o bá fẹ́ lọ fún ìsinmi lẹ́yìn Covid 19
- Wo bi wọ́n ṣe n ṣe àmójútó ilé ìjọsìn Prophet Israel Oladele, CCC Genesis Global
- Seyi Makinde fún olórin Fuji Taye Currency lẹ́bùn ọkọ̀ bọ̀kìnnì Toyota Prado 2020
- Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí gbogbo ọkọ̀ agbépo kúrò ní márosẹ̀ Lagos-Ibadan

Awọn ipa ti ọrọ aje to dẹnu kọle yoo ni lara rẹ:
Airi iṣẹ ṣe -
Lasiko ti ọrọ aje ba dẹnu kọlẹ, awọn ileeṣẹ yoo din awọn nkan ti wọn ṣe sita ku, eyi to tumọ si pe oṣiṣẹ perete ni wọn yoo nilo.
Abajade iru igbesẹ naa ni pe awọn eeyan kan yoo padanu iṣẹ wọn lasiko yii.
Èlé lori idokoowo yoo ja walẹ -
Lasiko ti ọrọ aje orilẹ-ede ko ba lọ deede, èlé to n gun ori owo idokowo yoo ja walẹ.
Idi ni pe, bi awọn eeyan ṣe n ra nkan yoo dinku, Banki Apapọ naa yoo si ma a gbiyanju lati ko owo jade lati fi ẹsẹ ọrọ aje mulẹ.

Oríṣun àwòrán, other
Ijọba yoo ma a ya owo si -
Nitori iṣoro aisi iṣẹ, ijọba yoo nilo lati na owo ju ti tẹlẹ lọ. Ọna ti wọn o gbegba ni pe, adinku yoo ba owo ori, ti wọn o si fi kun bi ijọba ṣe n nawo.
Ọja ipin idokowo yoo ja walẹ -
O ṣe e ṣe ki ọja ti wọn ti n ta ipin idokoowo ja walẹ, nitori pe èrè to n wọle fun awọn ileeṣẹ ti dinku.
Araalu ko ni le dokoowo daadaa -
Idi ni pe ibẹru ko ni jẹ ki awọn ileeọẹ gbe awọn igbesẹ kan lati gba awọn oludokoowo. O si tun le nira lati yawo ni banki.
Yatọ ti ti awọn ileeṣẹ aladani, ijọba paapaa yoo ṣe atungbeyẹwo awọn akanṣe iṣẹ, eyi to le mu ki awọn eeyan kan padanu iṣẹ wọn.
- Wòlíì Genesis kan yẹra díẹ̀ ni, ó máa tó wọlé padà bí olè lóru- Adelé pásítọ̀ Oladele
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
- Ṣé Sanwo-Olu, gómìnà Eko yóò farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate?
- A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn
Àwọn ìgbésẹ̀ tí SERAP ń fẹ́ kí ìjọba gbé lórí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó dẹnukọlẹ̀
Ìjọba orílẹ́-èdè Nàìjíríà tí kéde lójọ́ sátidé pé ọrọ̀ ajé rẹ̀ ti dẹnukọlẹ̀ pátápáta báyìí láti inú oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ ọdún 2020.
Àkọsílẹ̀ NBS fi han pé ìdàgbàsókè owó epo rọ̀ọ̀bì (Oil GDP) wa lára àwọn owó wa já wálẹ̀ jùlọ lásìkò yìí, ó si ti fí ìdá mẹ́tàlá ati díẹ̀ súnkì nínú ìdá ọgọ́rùn.
Inú oṣù kẹ́jọ ọdún 2016 ní ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Naìjìríà ti dẹnukọlẹ̀ kẹ́yìn.
Owó epo rọ̀ọ̀bì ni Nàìjíríà fí ń ri ìdá mọ́rùndínláádọ́rin owó tó n wọ́le fún ìjọba àpapọ̀, èyí túmọ̀ sí pé, tí wàhálà bá ti de ba ọ̀rọ̀ epo lágbàyé, ó ti di dandan ki Nàìjíríà fi ẹnu fẹ́ra.
Yàtọ̀ sí ǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2016, ó jọ bí ẹni pé, ìdẹnukọlẹ̀, ọ̀rọ̀ ajé tí àsìkò yìí yóò buru ju ti àsìkò 2016 lọ
Kíni à ń pè ní ọ̀rọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ (Reccession)
Ọrọ̀ ajé dẹnukọlẹ̀ ti àwọn ǹkan ti orílẹ̀-èdè ń pèsè fún títà (GDP) kò bá ko ba kún ojú oṣùwọ̀n dáadáa fún oṣù mẹ́rín -mẹ́rìn tẹ̀lé ara wọn.
GDP ni àpapọ̀ owó tàbi odiwọ̀n ọjà ti orílẹ̀-èdè kan ń pèsè lábẹ́lé láti tà fún orílẹ̀-èdè míràn
Bí ọ̀rọ̀ ajẹ Naijiria se wá dẹnukọlẹ̀ yìí, ó túmọ sí pé owó tí yóò máa wọlé fún ọjọ́ ti wọ́n tà síta óò maa kéré jọjọ.
Báwo ni yóò ṣe kan èmí àti ìwọ?
Fún kátàkárà, yóò kan iye owó ti yoo ma wọlé, owó tí àwọn ènìyàn yóò fi maa dọókoowo yóò gọbọi, yóò si níra láti ri ọjà tà.
Ìjọba pẹ̀lú yóò ṣe atúngbéyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ òde ti wọ́n ń ṣe lọ́wọ́, tàbi ki wọ́n dá àwọn iṣẹ́ náà dúró, èyí túmọ̀ sí pé, iṣẹ́ yóò bọ́ lọ́wọ́ àwọn kan.
Ọ̀pọ̀ àwọn olókoowò kéékèké àti àwọn onílé iṣẹ́ náà yóò din àwọn òṣìṣẹ́ kù la'ti kójú ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun yii, èyí ni àlàyé Nairametrics
Idénukọlẹ̀ ọ̀rọ̀ ajé lásìkò ààré Buhari
Ìgbà kẹta rèé ti ọ̀rọ̀ ajé Nàìjíríà yóò dẹnukọlẹ̀ lábẹ́ àkósò ààrẹ Muhammadu Buhari
Gẹ́gẹ́ bi ìwé ìròyìn Reuters ṣe sọ ọ̀rọ̀ ajẹ́ Nàìjíríà ti dẹ̀núkọlẹ̀ rí láti ọdún 1882 sí 1984, láye ìgbà náà ni ààrẹ Buhari wà ní ààrẹ ológun ní Nàìjíríà láàrí ọdún 1983 si 1985 lẹ́yìn ti wan dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ Shehu Shagari.
Bákan náà láàrín oṣù kérin sí oṣù kẹfà ọdún 2016, ọ̀rọ̀ ajé Naijiria dẹnukọlẹ̀f;ún ìdá 2.06%
Ẹ̀wẹ̀, àjọ SERAP ti ké si ìjọba Muhammadu Buhari pé ó ṣe pàtàkì ni àsìkò yìí láti mú àdínkù bá àwọn ìlànà ìṣèjọba kan kìí ṣe díndín owó òṣì'sẹ́ ìjọba ku ló ṣe pàtàkì.

Oríṣun àwòrán, SERAP
Wọ́n ni ó ṣe pàtàkì kí ó fi àwọn aláíní àti tálákà ṣe àkọ́ka nínú ìpnu rẹ̀ ni àsìkò yìí.
SERAP rọ ààrẹ Buhari láti mú àdínkù bá owó ààbò fún àwọn Gómìnà ìpińlẹ̀ (Security Vote) kí àtúnse ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà sì lọ dúró jẹ́ náà, tó fi mọ́ owó ńla tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin ń gbà.
SERAP rọ ìjọba láti ṣe amúlo ìmọ̀ràn yìí láàrín ọjọ́ mẹ́rìnlá tí wọ́n bá ti rí ìwé ẹ̀bẹ̀ SERAP gbà, àti pé tí ìjọba bá kọ láti 'se bẹ́ẹ̀, gbogbo ǹkan tó ba wà ni ìkáwọ́n rẹ̀ nílànà òfin ni òun yoo fi mú ijọba ṣe e

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Iná ètò ọrọ̀ ajé Naijiria jó àjórẹ̀yìn fún ìgbà kejì láàrín ọdun mẹ́rin
Ijọba apapọ ti kede pe nnkan ko fararọ lọwọ yii nitori pe ifasẹyin ti de ba eto ọrọ aje Naijiria.
Abajade iwadii ti ajọ oluṣeṣiro, National Bureau of Statistics, NBS, ṣe fi han pe adinkun ti de ba iye ida okoowo to n jade ni Naijiria ni iwọn 3.62%.
NBS sọ pe iṣẹlẹ naa ko ṣeyin ajakalẹ arun Coronavirus to n ba gbogbo agbaye finra.
Gẹgẹ bi awọn onimọ nipa eto ọrọ aje ṣe sọ, ti ọrọ aje orilẹ-ede ba ti ja walẹ lere-lera laarin abala meji ọdun kan, o n tumọ si pe ifasẹyin ti de ba ọrọ aje irufẹ orilẹ-ede beẹ niyẹn.
Ọdun 2016 ni ifasẹyin de ba eto ọrọ aje Naijiria kẹyin, iyẹn lasiko ti owo epo rọbi ja walẹ kaakiri agbaye.
- Ṣé Sanwo-Olu, gómìnà Eko yóò farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate?
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn
- Ọkùnrin tó pe ìyàwó rẹ̀ lájẹ̀ẹ́ tì í mọ́lé fọ́dún mẹ́rin, fún un lóyún nígbà mẹ́ta!
Wọn ni ifaṣeyin ọdun 2020 yii lo buru ni Naijiria lati ọdun 1987.
Naijiria gbojule owo epo rọbi fun ida marundinlaadọrin owo to n pa wọle, eyii to mu ki iye owo epo maa ṣakoso bi eto ọrọ aje rẹ yoo ṣe ri.
Ṣugbọn lọwọ yii, iye owo epo naa tun ti ja walẹ ju bi ijọba ṣe lero pe yoo ri lọ lati ọdun 2016.
- Saka ń wá ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nítorí aṣọ kóòtù ọdún 34 sẹ́yìn
- DSS ṣèlérí iwadìí tí kò rújú lórí bí òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan ṣe yìnbọn pa fẹ́ńdọ̀ lẹ̀yìn Gbajabiamila
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
- Bàbá mi, ẹ yé fi mí gba ìràwọ̀, ọmọbìnrin Charly Boy, Dewy Oputa fárígá fún bàbá rẹ̀




















