9ice Marriage: Ẹ ba mi bẹ ìyàwó mi, òun ni igi lẹ́yìn ọgbà mi

9ice

Oríṣun àwòrán, 9iceofficial

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja olorin takasufe, Alexander Abolore Adegbola Akande, ti ọpọ eeyan mọ si 9ice ti ke gbajare si awọn ọmọ Naijiria lati ba a bẹ iyawo rẹ ki igbeyawo rẹ ma baa fori sogi.

9ice lo n rawọ ẹbẹ si awọn ololufẹ rẹ bẹẹ ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ ni irọlẹ ọjọ Abamẹta.

O ni "mo ti ṣe ohun itiju ati ohun to buru jai eyii to fẹ tu ẹbi mi ka."

Abolore tẹsiwaju pe oun ko jẹ ohun kankan lai si iyawo oun nitori ọla obinrin naa ni oun jẹ.

9ice

Oríṣun àwòrán, 9iceofficial

O ṣalaye pe "Mo tọrọ aforiji lọwọ iyawo mi fun ohun ti mo ṣe, bẹẹ ni mo nilo iranlọwọ yin lati bẹ iyawo mi fun aṣiṣẹ nla yii nitori oun ni igi lẹyin ọgba mi."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun ti ṣe ọpọlọpọ aṣeyọri nile aye, ṣugbọn oun ko ṣe daadaa to ninu gbeyawo oun.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

9ice sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ti ṣe ọpọ aṣiṣe, ṣugbọn oun nilo iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria lati ba oun bẹ iyawo oun ki igbeyawo naa ma baa tuka.

Bo tilẹ jẹ pe 9ice ko sọ irufẹ ẹṣẹ to ṣẹ iyawo rẹ, eyii to fa ṣabababi ẹbẹ to n bẹ, ṣugbọn awọn eeyan kan ti n ṣo pe ko le e ṣeyin fidio to lu jade lori ayelujara laipẹ yii, eyi to ṣafihan bo ṣe gba obinrin kan mu nigba aya.

Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe olorin ọhun kundun obinrin lẹyin ti obinrin mẹta ọtọtọ ti bi ọmọ marun un fun un ko to fẹ iyawo rẹ, Olasunkanmi Akande.

Àkọlé fídíò, Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ekiti