Prophet Israel Oladele: Àwọn ìlúmọ̀ọ́ka tó ti jọ́sìn ní ijọ CCC, Genesis Global rèé

K1 DE Ultimate, Gani Adams, Oladele Ogundipe ati Woli Agba

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ọpọ eeyan lo ṣi n sọrọ lori idajọ ẹwọn ọdun meji ti ileẹjọ da fun oludari ati alakoso ijọ Celestial Church of Christ, Genesis Global Israel Oladele Ogundipe (GENESIS) lori ẹsun gbajuẹ.

Ileeṣẹ BBC Yoruba ti ṣe oriṣiiriṣii akojọpọ iroyin lori ọrọ yii lati igba ti idajọ ọhun ti jade.

A o tun ṣe ayẹwo awọn gbajugbaja lawujọ to ti jọsin ri ni ijọ CCC, Genesis Global Israel Oladele Ogundipe (GENESIS).

Gani Adams

Iba Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Gbedu, Genesis Global

Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams wa lara awọn ilumọọka to ti jọsin niijọ Celestial CCC (GENESIS) labẹ akoso pasitọ Ogundipe.

Aarẹ Ọnakakanfo lọ ṣe idupẹ ni ijọ Genesis Global, fọnran isin naa si lu ori ayelujara pa lẹyin to jọsin tan nibẹ.

Gani Adams sọ ninu ọrọ rẹ pe Pasitọ Ogundipe wa lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun toun bu ọla fun julọ lorilẹede Naijiria.

''Ẹmi irẹlẹ ti mo ri lara Pasitọ Oladele lo mu mi lọ ṣe idupe ninu ijọ rẹ,'' Gani Adams lo sọ bẹẹ.

Gani Adams tun sọ pe Pasitọ Oladele jẹ iranṣẹ Ọlọrun ti o ni ẹmi Ọlọrun.

''Bi mo ṣe jẹ aarẹ Ọnakakanfo wa lara asọtẹlẹ ti pasitọ Oladele sọ nipa mi eyi to wa si imuṣẹ,'' Gani Adams lo woye bẹẹ.

Wasiu Ayinde K1 De Ultimate

Wasiu Ayinde ati Oluṣọ Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

Alhaji Wasiu Ayinde K1 De Ultimate naa lara awọn ilumọọka to ti ṣabẹwo si ijọ Celestial CCC (GENESIS) labẹ akoso pasitọ Ogundipe.

K1 De Ultimate ṣere ninu ijọ naa pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ.

Alhaji Ayinde kọ ninu orin nibẹ pe ayọ ni fun gbogbo awọn ijọ Genesis ati fun oun naa to fi mọ idile oun.

Wasiu tun kọ ninu orin pe awọn to n binu Pasitọ Ogundipe le maa binu lasan nitori ẹni ti Ọlọrun gba fun un ni.

K1 De Ultimate tun ki gbogbo awọn alatilẹyin Pasitọ Oladele ninu orin rẹ bakan naa.

Pasitọ Ogundipe naa dupẹ lọwọ K1 De Ultimate pẹlu idọbalẹ, bakan naa lo tun gbadura fun olorin naa.

Woli Agba ati Dele Omo Woli

Woli Agba ati ikọ ere ori itage rẹ

Oríṣun àwòrán, Woli Agba Ayo Ajewole

Adẹrinpoṣonu, Ayo Ajewole ti ọpọ mọ si Woli Agba ati iṣọmọgbe rẹ, Mide Oladimeji ti ọpọ mọ si Dele ọmọ Woli naa ṣabẹwo si Genesis Global.

Woli Agba ati Dele fi ijo bẹẹ niwaju ijọ lasiko ti isin n lọ lọwọ, koda Pasitọ Ogundipe naa ko gbẹyin.

Woli Agba ati Dele pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ lo pitu meje ti ọdẹ n pa ninu igbo pẹlu ere ori itage ti wọn da awọn ọmọ ijọ naa laraya.

Pasitọ Ogundipe fi ẹmi imoore han nipa gbigba adura fun Woli Agba atawọn ọmọlẹyin rẹ pe oke oke lẹyẹ n fọ un pe loke loke ni yoo maa lọ.

Chief Commander Ebenezer Obey

Akọrin Juju tẹlẹ to ti di ajihinrere papaa julọ ninu orin kikọ bayii, Chief Commander Ebenezer Obey naa ti lọ ṣere ninu ijọ Genesis Global.

Ki Obey to bẹrẹ ere niwaju ijọ naa, o kọkọ bu adura julẹ fun Pasitọ Ogundipe.

O beere fun ilọsiwaju ohun rere gbogbo ti Eleduwa n ṣe lati ọwọ pasitọ naa.

Koda, gbajugbaja akọroyin Dele Momodu naa wa labẹ isin nigba ti Obey ṣere ninu ijọ Genesis Global.

9ice ati Atorise

Atorise

Oríṣun àwòrán, Alanre Teriba

Gbajugbaja olorin takasufe, Abolore Adegbola ti ọpọ mọ si 9ice ati Lanre Teriba ti wọn n pe ni Atorise naa ṣere ni ṣọọṣi Genesis Global.

9ice kọ oriṣiiriṣii orin to ti gbe jade ninu awo rẹ niwaju ijọ Genesis Global.

Atorise naa da orin bolẹ niwaju ijọ Genesis Global.

Niṣe ni Atoriṣe n yira mọlẹ nigba ti o n kọrin da awọn ọmọ ijọ lara ya.