Professor Peller: Ọlọ́wọ́ idán àkọ́kọ́ nílẹ̀ Áfíríkà tó ń pidán fáwọn aṣaájú orílẹ̀èdè

Abiola Peller

Oríṣun àwòrán, Intagram/shinapeller

Bi ogun ẹni ba da ni loju, aa fi gbari ni, ohun ti eeyan ba si mọ se, bi idan lo n ri.

Ọrọ Ọjọgbọn Moshood Folorunso Abiola Peller kii se ohun ti eeyan le sọ tan ni oojọ, asọpati ni nitori ọpọ isẹ aramọnda idan pipa to gbe ile aye se.

Fun awọn ọdọ iwoyii, wọn le ma ranti awọn pidanpidan mii tabi ri wọn wo loju aye nitori asa idan pipa ti n lọ sokun igbagbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn ko si ọmọ Naijiria tabi ọmọ ilẹ Kaarọ Oojire to ti to ogoji ọdun, ti ko ni ranti orukọ Professor Peller, ni kete to ba gbọ.

Bi onirese Peller ko ba si fin igba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ, ko le lọ sokun igbagbe laelae nitori titi aye la maa se iranti rẹ.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

A ko si le gbagbe awọn ipa to ko si agbega iran Yoruba lati ipasẹ isẹ to yan laayo, tii se idan pipa.

Bi itan igbe aye ati diẹ lara awọn ohun ti akọni ọlọwọ idan, Ọjọgbọn Abiola Peller gbe ile aye se ree, ko to silẹ bora.

Ibẹrẹ igbe aye Abiola Peller:

Ilu Isẹyin, lagbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo ni wọn ti bi Ọjọgbọn Moshood Folorunso Abiola Peller, ti ọpọ mọ si Professor Peller ni ọdun 1941.

Idile Musulumi pọnbele lo ti jade gẹgẹ bi ẹsin naa se wọpọ nilu Isẹyin, Moshudi olori pupa si ni inagijẹ rẹ nigba to wa ni kekere.

Idi ni pe eeyan pupa ni Abiola Peller, ti irun ori rẹ si pọn bii osun, amọ to n dudu diẹdiẹ nigba to dagba.

Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Musulumi ati Native Authority nilu Isẹyin lo ti ka iwe alakọbẹrẹ rẹ, ko to morile ilu Ibadan.

Ilu Ibadan yii si lo ti bẹrẹ isẹ idan pipa lọdun 1954, to si n lọ yika Ibadan, Eko ati Oyo lati pidan.

Abiola Peller

Oríṣun àwòrán, Intagram/shinapeller

Ọdun kan aabọ ni Peller lo nilẹ India lati kọsẹ idan pipa:

Amọ nigba to di ọdun 1959, Peller pa isẹ da, to si di asoju ileesẹ ontaja G.B.O ati ilumọọka onisowo pẹrẹu.

Sugbọn niwọn igba to jẹ pe abinibi yatọ si adayekọ, isẹ idan to wa ninu ẹjẹ Peller ko se bo mọlẹ, idi si ree to fi tun pada sidi isẹ naa lọdun 1964.

Nibayii, ilẹ India ni Peller gba lọ lati lọ wa imọ kun imọ rẹ ninu idan pipa, se gbogbo agbaye lo kuku mọ pe orilẹ-ede India ni ile idan pipa.

Ọdun kan ati aabọ ni Peller lo ni India lati fi kọ isẹ idan pipa si, o wa morile orilẹ-ede Liberia lati tẹdo si nigba to kuro ni India.

Nigba to di ọdun 1966, lo tun pada wa sile nitori ajo ko dabi ile, to si bẹrẹ si ni fi isẹ idan pipa pa ọwọ da.

Ko tii si ẹni kan to le pidan bii Peller, baba ọlọwọ idan lẹyin iku rẹ:

Yoruba ni arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ta ba gbe ile aye se loni, yoo di itan to ba di ọla.

Bẹẹ ni ọrọ awọn aseyọri aramanda ti Ọjọgbọn Peller fi idan da nigba aye rẹ.

Ẹnikan kii ba Yinmiyinmi du imi si lọrọ rẹ, to ba di ibi ka pidan, to le mu omi loju ẹni tabi mu ki aya ẹni ja de idi.

Ni orilẹ-ede Naijiria ati Afirika lapapọ, ẹyẹ ti yoo se bii ọkin ko si lawujọ ẹyẹ ni ọrọ idan Abiola Peller, ti gbogbo eeyan si gba pe oun ni pidanpidan to dantọ julọ.

Koda, lẹyin ti Peller papoda, ko tii si ẹni kan to le pidan bii baba ọlọwọ idan yii.

Bo si se n la ẹnu ọba silẹ lasiko iworan idan rẹ, naa ni ero iworan yoo sẹmi lọ ti idan Peller ba wọra ja.

Koda, fasiti kan nilẹ Gẹẹsi, University of Birmingham gan an ko le gbagbe idan nla kan ti Peller pa ni papa isere King George V lọdun 1972, eyi to wa pada di papa isere Onikan lonii.

Abiola Peller ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Intagram/shinapeller

Oniruuru idan aramanda ti Peller pa nigba aye rẹ:

  • Peller na obinrin kan, (tii se iyawo rẹ) fẹlẹfẹlẹ sinu posi, to si ge e si meji lai yọ ẹjẹ jade, to si tun ji i pada sile aye
  • O tun ti obinrin naa mọ inu Kọbọdu, o fi ẹwọn de kọbọdu naa mọlẹ, amọ nigba to si Kọbọdu naa, obinrin ọhun ti poora
  • Bakan naa bi Peller ba na asọ inuju rẹ funfun, taa mọ si Handkerchief soke ati isalẹ, ẹyẹ Adaba ni yoo fo jade
  • Ko tan sibẹ, bi Peller ba tun maa yọ irin meji to fi mu ọwọ asọ oloyinbo shirt to wọ, se ni yoo na wọn soke, ti wọn yoo si yipada di ododo
  • Peller tun ti gbe okuta mi ri loju gbogbo ero iworan, to si kọ ẹyin si wọn, to si ya okuta to gbe mi naa jade lati idi
  • Bakan naa ni Peller ti gbe ara rẹ silẹ ri, ti wọn fi ida ge e si meji, amọ to pada ji pada.

Fasiti Birmingham wa se apejuwe Peller bii akọni apidan to ni igboya, ọla ati akikanju lara, ti idan to n pa si rọ ọ lrun pupọ.

Awọn akọni asaaju awujọ ati orilẹ-ede ti Peller ti fi idan da lara ya:

Lara awọn asaaju orilẹ-ede ti Peller ti fi idan da laraya ni aarẹ ilẹ Togo to ti di oloogbe, Gnassingbe Eyadema ati Samuel Kanyon Doe ti orilẹ-ede Liberia ati aarẹ ilẹ Benin, Mathieu Kerekou.

Kii kuku se pe Peller ati Samuel Doe sadede di ọrẹ, se bi o lọ pidan lọdun 1970 ni nilu Monrovia, ti ero si ya si papa to ti n pidan naa.

Eyi lo si mu ki ijọba Liberia tete ko awọn agbofinro da sagbegbe naa lati ri i pe ohun gbogbo lọ leto leto, lara awọn agbofinro to wa nibẹ naa si ni Samuel Doe.

Se ẹyin lo n di akukọ, nigba to ya, Samuel Doe pada di aarẹ ilẹ Liberia lati ipasẹ iditẹ gbajọba, to si kesi Peller pe ko wa fi idan da oun naa lara ya.

Bakan naa nilẹ wa Naijiria, Oloye Obafemi Awolowo naa wa lara awọn asaaju oloselu to gbadun idan Peller, lasiko to fi jẹ olootu ijọba ẹkun Iwọ oorun guusu Naijiria.

Abiola Peller ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Intagram/shinapeller

Ọrọ ifẹ ati igbeyawo Abiola Peller:

Wọn se apejuwe Peller bi eeyan to ni ifẹ pupọ, ti oun ati aya rẹ, Alhaja Silifat Adeboyin Peller si nifẹ ara awọn nigba ti onitọun wa nile ẹkọ girama.

A gbọ pe Peller lọ pidan nile ẹkọ girama iseyin District Grammar School lọdun 1967 ni, lo ba foju kan arẹwa obinrin naa laarin awọn akẹkọ to wa woran.

Ibẹ ni wọn ti fi eso ifẹ lọlẹ, eyi to dagba di igi alọye, to si so eso rere, ti ọmọge ọjọ naa si di Lady Peller, to n ba ọkọ rẹ sere idan.

Ọdun 1971 ni wọn se igbeyawo, ti wọn si bi isu ati iwalẹ fun ara wọn.

Bi o tilẹ jẹ pe Abiola Peller fẹ ọpọ obinrin bii aya, ti wọn si se abiyamọ fun, amọ eyi ti okiki rẹ kan julọ, ti aye si mọ mọ baba ọlọwọ idan naa ni Lady Peller.

Iku ati igbẹyin aye Moshood Folorunso Abiola Peller:

Ọjọ nla, ọjọ manigbagbe ni ọjọ keji, osu Kẹjọ, ọdun 1997 ti iku wọle wẹrẹ, to si mu baba ọlọwọ idan lọ nile rẹ ladugbo onipaanu nilu Eko.

Inu ile rẹ yii lo wa ni ọjọ naa, lọwọ aago meje alẹ, to sẹsẹ ti ode de, to si n kirun alẹ lọwọ, ti awọn abẹnipa-gbowo wọle tọ wa, ti wọn si da ẹmi rẹ legbodo.

Ori irun kiki ni iku airotẹlẹ naa de ba Peller, ti wọn si fi ibọn pa, bẹẹ ni ko si ẹni to le sọ awọn eeyan to wa nidi isẹlẹ naa ati idi ti wọn fi se bẹẹ, titi di akoko yii.

Ọdun mẹrindinlọgọta pere ni akọni ọlọwọ idan yii lo loke eepẹ, ki wọn to ja okun ẹmi rẹ lainidi.

Silifat Adeboyin Peller

Oríṣun àwòrán, Instagram/ladypeller

Yoruba ni bi ina ba ku, a fi eeru boju, bi ọgẹdẹ ba si ku, yoo fi ọmọ rọpo, bi oloye ba ku, o sa maa n fi oloye silẹ ni.

Ọba oke fi awọn ọmọ oloriire lọkunrin lobinrin jinki Abiola Peller, ti gbogbo wọn si n gbe oke eepẹ se rere lọjọ oni.

Koda, ọmọ rẹ kan, Shina Peller ni asoju-sofin to n soju ẹkun idibo isẹyin, Itesiwaju, Kajola ati Iwajowa nipinlẹ Oyo, nile asoju sofin apapọ bayii.

A wa n gbadura pe ki Ọba Oke fi ọrun kẹ baba ọlọwọ idan, Ọjọgbọn Moshood Folorunso Abiola Peller.

Itan ti igbe aye Abiola Peller kọ wa:

Ohun pataki ta ri kọ ninu itan aye akọni ọlọwọ idan yii ni pe ka mase fi àrà sinu ku.

Gbogbo abuda ati ọgbọn atinuda ti Ọba oke ba fun wa lati ọrun, ni ka maa lo fun agbelarugẹ iran ọmọniyan.

Bi Abiola Peller ko tilẹ pẹ pupọ laye, ki wọn to ran sọrun ọsan gangan, sibẹ, ipa kekere kọ lo ko lati mu ki ẹmi ẹda gun si pẹlu ọwọ idan to ni.

Ipokipo ti ẹda ba si wa, ipa rere ta le fi lelẹ fun agbega iran ọmọniyan, ni ka jẹ ko jẹ wa logun.

Ọjọgbọn Moshood Folorunso Abiola Peller, ọrun re rẹ o.

Abiola Peller ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Intagram/shinapeller