Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle tó ń mu oògùn olóró, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí láti pè é padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run
Ni ọpọ igba ni a maa n ri awọn ọmọ lile ni ayika wa, ta si maa beere pe iru ile wo ni wọn ti jade wa, tabi obi wo gan lo bi iru awọn ọmọ buruku yii.
Iru awọn ọmọ bẹẹ le e maa jale, wa ninu ẹgbẹ okunkun, maa pa eeyan, mu oogun oloro, fi ipa ba ni lopọ tabi maa ja kiri adugbo.
Nigba miran, ni ọpọ wọn maa n wa lati inu ile rere, ti awọn obi wọn si le gbajumọ lawujọ tabi jẹ olowo, ọmọwe tabi ojisẹ Ọlọọrun bii Pasitọ ati Aafa.
Awọn eeyan to ba si ba iru awọn ọmọ bẹẹ pade, ti wọn si mọ inu ile rere ti wọn ti jade wa, ni yoo maa beere pe ki lo de ta bi ọmọ yii ni isọ aguntan amọ to ya isọ ewurẹ lọ ree jẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ́, fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Sina Jesu ní orúkọ́ mi báyìí, ń kò jẹ́ Shina Rambo mọ́ - Adigunjalè tẹ́lẹ̀ kìlọ̀
- Wòlí àti Pásítọ́ ló máa ń rọ̀jọ̀ àdúrà sórí ibọ́n wa kí a tó lọ digunjalè- Kayode Williams
- Mo di afọ́jú lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí aya mi kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ - Wòlíì Oluwalogbon
- Kò yẹ kí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run máa kiri ilé ìjọba, kí ni wọ́n ń wá? - Timi Osukoya
- Pásítọ̀ Adejare Adeboye rọ òjò àdúrà sórí ọmọ Nàíjíríà lọ́dún tuntun
- Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mo ti ń bá Adẹ́rùpọkọ̀ ṣe eré tíátà - Tope Alabi
- Gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí ṣe panságà, ó kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí aya rẹ̀
- Ìjọ Islam fìwé pe Wòlíì Genesis bíi àlejò pàtàkì sí òru Lailatul Quadir, ariwo sọ
Ọpọ awọn obi to ba si ni iru awọn ọmọ bayii lo ti maa n ro wọn pin pe ohun rere kankan ko tun le ti ọdọ wọn jade wa mọ.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu idile Adetuberu ti ọkọ ati aya jẹ ojisẹ amọ ti akọbi wọn jẹ ẹni to n mu oogun oloro nigba to wa nile ẹkọ fasiti.
Ọmọ ọdun marun ni mo ti n waasu amọ mo fẹ se bii awọn ẹgbẹ mi, lo sọ mi di ẹni to n mu egbogi oloro – Wolii G.F Adetuberu
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Wolii G.F Adetuberu salaye pe ọmọ ọdun mẹrin ni oun ti maa n waasu, ti oun si mọ Ọlọrun lati kekere aye oun.
O ni oun ko le sere tabi huwa bii awọn akẹẹgbẹ oun nitori oun gbe isẹ Oluwa sori lati igba ewe.
Amọ nigba ti oun fẹ wọ ile ẹkọ fasiti, ni oun ri ara oun bii ẹni ti ko ‘Normal’, ti oun si pinnu lati Normal, ki oun lee se bii awọn akẹẹgbẹ oun.
“Asiko yii ni mo bẹrẹ si huwa ti ko dara, mo n mu ọti, ti mo si n mu egboogi oloro fun ọdun mẹfa ati abọ.
Ijakulẹ ti mo ba pade lo mu ki n yi ero mi pada pe o dara ki n pada si ọdọ Ọlọrun , ti mo si lọ ba Ọlọrun laja.
Amọ ni gbogbo akoko ti mo n huwa kotọ yii, awọn obi mi ko sọrọ odi si mi ri, wọn ko ni aye mi bajẹ, wn kan maa n ni ẹgbẹrun Saamu mi, ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ.
Loni, mo di wolii agbaye, o si yẹ ki awn obi to ba ni ọmọ lile fi itan aye mi se arikọgbọn ati ipa rere ti awọn obi mi ko lati pe mi pada.
Obi to ba n sepe fun ọmọ lile n fi ontẹ tẹ pe ko ni se rere ni – Funke Adetuberu
Ilumọọka oniwaasu ori redio ati ayelujara ni Pasitọ Funke Adetuberu, o si ni ibujoko nilu Ibadan.
Bakan naa lo maa n gba ọpọ idile to n la isoro kọja niyanju lori ọna ti wọn yoo gba bori isoro wn.
Amọ oju ojisẹ Ọlọrun lobinrin naa ti ri to lasiko ti akọbi ọmọ rẹ n dagba, eyi to yẹ ki ọpọ eeyan fi se arikọgbọn.
Nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, Pasitọ Funke Adetuberu ni ko yẹ ki obi maa sepe fun ọmọ to ba le nitori epe sisẹ sori ọmọ lati ẹnu obi jẹ ontẹ.
O ni iwa abinibi to mu ki ọmọ yẹn le gan ni ogo rẹ fi maa han lọjọ iwaju, bẹẹ si ni gbogbo ọmọ lile ta ri loni yii ni ọbẹ fun obi lọjọ ọla nitori nnkan gidi wa ninu iwa ipanle.
“Nigba ti akọbi mi to di wolii agbaye lonii n mu egbogi oloro, mo sọkun kikoro, ti mo si sọ fun Ọlọrun pe ko sanwo isẹ mi lori ọmọ naa, to ba jẹ pe lootọ, ojisẹ rẹ ni mo jẹ.
Ọlọrun pada gbọ adura mi, to si yi ọmọ naa pada si ojisẹ Ọlọrun.
Lati ọmọ ọdun marun lo ti maa n waasu, ko to wa di ẹni to n mu egbogi oloro amọ nipa adura, o ri aanu gba pada.
Imọran fun awọn obi to ni ọmọ lile:
Wolii G.F Adetuberu ati mama rẹ, Funke wa gba awọn obi nimọran pe ki wọn maa se adura fawọn ọmọ lile lo tọ.
Wọn ni ko dara ki wọn maa fi ẹnu odi ba wọn sọrọ nitori ohun rere si le jade lati ara ọmọ lile pẹlu adura.





