Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé

Àkọlé fídíò, Timi Osukoya: Ọ̀pọ̀ olórin ẹ̀mí ló ń kọrin torí owó tàbí afẹ ayé

Kii se tuntun mọ lati maa ri awọn olorin ẹmi, paapaa nilana Kristiẹni, ti wọn n kọrin tabi jo bo se wu wọn.

Koda, ọpọ eeyan ni ẹnu maa n ya lasiko yii nipa imura, orin kikọ ati ijo jijo awọn olorin ẹmi, eyi ti ko yatọ si ti aye.

Ọrọ yii si lo ti n ka gbajugbaja olorin ẹmi kan, Ajihinrere Timi Osukoya, lara, ẹni to ti kọ oniruuru orin ẹmi lati jere ọkan ni ọpọ ọdun sẹyin.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Osukoya ni ẹmi mimọ lo maa n dari awọn olorin ẹmi bii toun ni ọpọ ọdun sẹyin, nipa orin ti awọn yoo gbe jade.

Amọ lode oni, o ni ọpọ akọrin ẹmi lo kan n kọrin gẹgẹ bi ara ohun to fẹran julọ lati maa se tabi gẹgẹ bi ọna lati fi pa owo wọle.

Bakan naa lo fikun pe baba oun, to jẹ pasitọ lo wu oun lori lati maa kọrin ẹmi, to si fi ireti han pe ọjọ ọla yoo dara fun gbogbo eeyan lati gbe.

Bakan naa lo koro oju si awọn ojisẹ Ọlọrun lati maa lọ sile ijọba, to si n beere pe ki ni wọn n wa?

O wa rọ awọn olorin ẹmi lati mase jẹ ki ifẹ aye gba ẹmi Ọlọrun lọwọ wọn