Hunger in Afghanistan: Ọkọ àti ìyàwó ta ọmọ wọn ní N200,000 nítoró ìṣẹ́

Ọmọdebinrin ni Afghanistan

Yoruba bọ, wọn ni ti ebi ba kuro ninu iṣẹ, iṣẹ buṣe.

Ṣugbọn ọrọ ebi nikan kọ ni iṣoro to n koju awọn ọmọ orilẹede Afghanistan, papaa julọ lati igba ti ẹgbẹ Taliban ti gba ijọba nibẹ.

Rukerudo, rogbodiyan ati oriṣiiriṣii ajalu lo ti n ṣẹlẹ kaakiri Afghanistan lati igba ti Taliban ti gba ijọba.

Gbogbo iranwọ ti Aghanistan n ri gba tẹlẹ lati ọdọ awọn orilẹede agbaaye to rọwọ họri ni ko si mọ bayii lati igba ti Taliban ti gori aleefa.

Laipẹ yii ni ajọ iṣọkan agbaye, UNO ke gbajare pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan ni Afghanistan ni ebi yoo pa ku ti orilẹede naa ko ba ri iranwọ lati ilẹ okeere.

Akọroyin BBC, Yogita Limaye to wa n Afghanistan jabọ pe ni ilu Herat ọpọlọpọ ẹbi ni atijẹ atimu nira fun.

Oriṣiiriṣii nkan lawọn obi n ṣe lati ri pe awọn ọmọ wọn ri ounjẹ jẹ.

Nibẹ ni a ti ri ọkọ ati iyawo kan ti wọn ta ọmọbinrin wọn ni ẹgbẹrun un lọna igba naira tii ṣe ẹẹdẹgbẹta owo dola, $500.

Iya ọmọdebinrin naa ṣalaye pe oun ati ọkọ oun pinnu lati ta ọmọ awọn ki awọn le ri owo ra ounjẹ fawọn ọmọ to ku.

Iya ọmọ naa ṣalaye pe ''ebi lo n pa wa ku lọ lo jẹ ki a ta ọmọdebinrin wa ki a ba le ri ounjẹ jẹ ni pẹlu awọn ọmọ wa to ku.

Ko wu mi ki n ta ọmọ mi amọ ohun to de lo ni ki a ri ohun.''

Iṣẹ ako idọti ni baba ọmọdebinrin yii n ṣe ṣugbọn owo perete ni o n ri nibẹ.

Baba ọmọ naa sọ pe ''ebi n pa wa, ko si iyẹfun, ko si ororo, a o ni ohun kankan.

Ọmọdebinrin mi ko mọ ohun to le ṣẹlẹ si i lọjọ iwaju bayii, mi o tiẹ mọ bo ya inu rẹ dun si bi a ṣe ta a.

Ṣugbọn ohun ti a gbọdọ ṣe ni nitori iṣoro airijẹ ati airi mu to n doju kọ wa.''

Kete ti ọmọ ba ti bẹrẹ si ni rin ni awọn obi wọn maa n ta wọn ni Afghanistan.