Coup attempt in Sudan: Ìròyìn n sọ pé ìdìtẹ̀ gbàjọba n wáyé lọ́wọ́ ní Sudan

Awọn araalu ti bọ si igboro fun iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọmọ ogun orilẹ-ede Sudan ti mu ọpọlọpọ awọn ọmọ igbimọ ijọba awaarawa si atimọle.

Bakan naa ni wọn ti ti ilẹkun mọ olootu ijọba, Abdalla Hamdok, mọ ile rẹ.

Awọn iroyin yii lo n jade lati orilẹ-ede Sudan, to wa ni Africa.

Lọwọlọwọ, akọsilẹ awọn nkan ti a mọ nipa iroyin naa niyii:

  • Awọn ọmọ ogun to di ihamọra ti tú jade si igboro olu-ilu orilẹ-ede naa, Khartoum bayii
  • Awọn araalu naa ti jade lọpọlọpọ lati sẹ iwọde tako iditẹ gbajọba
  • Oju opo ayelujara ko ṣiṣẹ mọ ni Khartoum.
  • Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn ọmọ ogun ti yabo ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ orilẹ-ede naa, ti wọn si mu awọn oṣiṣẹ kan.
  • Orilẹ-ede America sọ pe "ẹru n ba oun" lori iroyin to n jade ni Sudan

Ileesẹ ologun ko tii sọrọ lori isẹlẹ yii amọ awọn ẹgbẹ to fara mọ ijọba alagbada ti n pe fun iwọde oju popo.

Awọn araalu ti bọ si igboro fun iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ologun atawọn olori ẹgbẹ to n ja fun ijọba awarawa ti n tako ara wọn lati bi ọdun meji ti wọn ti doju ijọba Omar al-Bashir bolẹ.

Lẹyin igbakoso ijọba naa ni wọn se agbekalẹ awọn ọmọ igbimọ ti yoo da ijọba pada fun awọn alagbada.

Awọn araalu ti bọ si igboro fun iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko si ẹni to le sọ awọn to wa nidi bi wọn ṣe fi ọwọ ofin mu awọn eeyan naa ni idaji.

Amọ, atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ iroyin fi sita sọ pe awọn ikọ ologun kan lo wa nidi ọrọ naa.

Awọn araalu ti bọ si igboro fun iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

A n ṣi n ṣe akojọpọ iroyin yii lọwọ. Ẹ ma a kàn si oju opo yii loore-koore fun bi nkan ṣe n lọ ni orilẹ-ede Sudan.