Sheikh Gumi Naijiria yóò dàrú tí ìjọba àpapo bá lè kéde àwọn jàndùkú gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí

Sheikh Ahmad Gumi

Oríṣun àwòrán, El-gwadabar Khan

Adari ẹsin Musulumi, Sheikh Ahmad Gumi ti kilọ pe Naijiria yoo tuka ti ijọba ba le kede awọn janduku gẹgẹ bii agbesumọmi.

Gumi ni lootọ ni pe ihuwasi awọn janduku naa, paapaa lagbege Ariwa Naijiria fara pẹ ti awọn agbesumọmi, ṣugbọn gudugbẹ yoo ja ti Aarẹ Muhammadu Buhari ba le kede pe agbesumọmi ni awọn janduku ọhun.

Adari ẹsin Musulumi naa lo fi ọrọ ọhun lede ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ.

Ṣaaju ni awọn gomina kan, to fi mọ ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti kọkọ sọ pe ki Aarẹ Buhari kede awọn janduku naa ni agbesumọmi, ki ileeṣẹ ọmọ ogun ba le da sẹria fun wọn.

Ṣugbọn Gumi, to jẹ ajagunfẹyinti, ti ọpọ tun n wo gẹgẹ bii agbatẹru awọn janduku ọhun sọ pe nnkan ko ni fararọ ti ijọba apapọ ba le kede awọn eeyan naa gẹgẹ bi agbesumọmi.

O ni "lootọ ni pe awọn nkan ti awọn janduku yii n ṣe ti n farajọ iwa igbesunmọmi, nitori igbesumọmi ni iwa to ba le pa awọn araalu lara."

"Amọ ṣa, o yẹ ki ijọba tẹ ẹ jẹjẹ lori ọrọ awọn eeyan naa."

Gumi sọ pe akitiyan oun lati yi ọkan awọn janduku naa pada ti bẹrẹ si n so eso rere, bo tilẹ jẹ pe oun n ni awọn idojukọ diẹ ninu akitiyan naa.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Gẹgẹ bii ohun to sọ, oun ti n ba awọn janduku naa sọrọ ki wọn le yi iwa wọn pada, oun si lero pe awọn alufaa atawọn ojiṣẹ Ọlọrun yoo bẹrẹ si n ba awọn ajigbara IPOB naa sọrọ, to fi mọ awọn ajijagbara ilẹ Yoruba lati dẹkun dida omi alaafia Naijiria ru.

Gumi sọ pe "Mo lero pe awọn alufaa kan to jẹ ẹya Igbo yoo bẹrẹ si n ba awọn ajijagbara IPOB naa sọrọ bi mo ṣe n ṣe, ki wọn le yi ero wọn pada."

"Mo tun lero pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun nilẹ Yoruba naa yoo tun maa ba awọn ajijagbara Yoruba Nation naa sọrọ gẹgẹ bi mo ṣe n ṣe pẹlu awọn eeyan wọnyii ki alaafia le jọba."

Gumi pari ọrọ rẹ pe o ṣeeṣe ki awọn alaiṣẹ fara gba ninu atubọtan ohun ti yoo ṣẹlẹ ti ijọba apapọ ba kede awọn janduku gẹgẹ bii agbesumọmi.

Àkọlé fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou