Ogun Church Kidnapping: Agbébọn ń bèèrè N6m lórí èèyàn mẹ́ta tí wọn gbé ní ṣọ́ọ́ṣì

White garment church

Oríṣun àwòrán, Facebook: Olatunji Blessing

Ṣe ni ọrọ di boolọ, ko ya fun mi ni abule Obada Oko to wa ni agbegbe Ewekoro nipinlẹ Ogun nidaji ọjọ Aiku.

Idi ni pe se ni awọn gende agbebọn kan sadede ya wọ ile ijọsin Kerubu ati Serafu kan to wa loju ọna Reluwe, ti wọn si ji olujọsin mẹta gbe lọ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ti salaye, orukọ awọn eeyan mẹtẹẹta naa ni Ifeoluwa Alani-Bello, Adebare Oduntan and Mary Oliyide.

Awọn eeyan yii ni wọn n se iṣọ oru lọwọ saaju isin ọjọ isinmi, tawọn agbebọn si wọle wa gbe wọn lọ.

Iroyin naa ni awọn agbebọn ọhun ti n beere miliọnu mẹfa naira lọwọ awọn mọlẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe ọhun, ki wọn to ri idande gba.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni ileesẹ ọlọpaa ti fi awọn osisẹ rẹ sọwọ si agbegbe naa lati lọ kun awọn ọlọpaa to wa ni ẹkun Obada Oko lọwọ.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

O fikun pe ileesẹ ọlọpaa naa ti kilọ saaju fun awọn araalu lati dẹkun sise isọ oru ati isin ni awọn agbegbe to ba da.

Amọ o ni to ba jẹ dandan ki wọn se isin nibẹ, o yẹ ki iru awọn olujọsin bẹẹ fi to ileesẹ ọlọpaa leti fun ipese aabo to peye le wa fun wọn.

Àkọlé fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou