Ǹjẹ́ òbìnrín tún le lóyún lásìkò tó wà nínú oyún, kíní sáyẹ́nsì sọ?

Pregnant woman

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ó ṣeéṣe kí obìnrin lóyún lásìkò tó wà nínú oyún, bí o ṣe dábi ẹni pé kó jọ nǹkan tí ó ṣe é ṣe tó, òótọ́ ni, obìnrin lé ti lóyún kí o tún ni èyún mííràn.

"Superfetation" gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe ń pèé kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ sùgban ó máá n wáye gẹ́gẹ́ bi oyún ẹlẹ́kejìlẹ́yìn ti obìnrín bá ti ni oyún àkọ́kọ́.

Nítorí ìdí èyí, o túmọ sípé obìnrin náà lóyún ìbèjì, sùgban àsìkò ọtọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n yóò fi dàgbà, ní ọ̀ps ìgbà wọ́n kò ni bí wọn ni àsìkò kan náà.

Bí ó ti lé jẹ́ pé ìyàtọ wà láàrín kí ẹyin méjì so èso nílé ọmọ (Superfecundation) tabi kí obbìnrin ni oyún ni ṣíṣẹ̀ ń tẹ̀lé (Superfetation), ìkan jk kí ààtọ ọmọkúnrin lọ sí inú ẹyin méjì lásìkò ìbáṣepọ̀ kan láàrin oṣù( Superfecundation), ibèjí ni yóò fi irú oyún yìí bí.

Sùgbọ́n bi ti ìkejì (Superfetation) àsìkò nǹkan osù ọtọ̀ọ̀tọ̀ ló ni oyún méjì yìí, àwọn ọmọ méjèèjì náà yóò sì ni ìwọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ lásìkò ìbí, irú ẹ̀jẹ̀ wọn yóò yàtọ̀, kódà wọn le jẹ́ ọmọ bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ.

Bí obìnrín bá wà nínú oyún, ilé ọmọ rẹ̀ kò ni gbé ẹyìn jáde mọ́, t;i gbogbo èròjà tó n pètò ọmọ lára yóò sì máa sọ fun kí ó má agbáradì fún ọmọ bíbí.

Ó kéré tán àrídájú àpẹrẹ irú èyí mẹ́wàá ló ti ni àkọsílẹ̀, èyí tí o súmọ́ jùlọ lo wáyé ni orílẹ́-èdè Australia tí ó obìnrin kan ti orúkọ rl ń jẹ Kate Hill, tó ni oún ni ẹ̀ẹ̀mèjí láàrín ọjọ́ mẹ́wàá.

Ó bí àwọn ọmọ obìnrin, Charlotte àti Olivia, tí wọ́n sì ń pè wọ́n ni ìbejì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọjọ mẹ́wàá ni wọ́n gbà lọ́wọ́ ara wọn.

Àkọlé fídíò, Àwọn abirùn ọmọ tí òbí wọn tì mọ́lé ni mo lọ ń kó jáde láti máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ iléèwè - Sekinat Ahmed

Ọjọ́ kan náà ni wọ́n bi àwọn méjèèjì, sùgbọ̀n wan ni ìwọ̀n ọ̀ọ̀tọọtọ àti irú ẹ̀jẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ.

Àwọn ẹrànko máá ń bí ibejì èyí sì wọ́pọ̀ láàrrín Èkúté, Ehoro, Àgùtàn, bákan náà lo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ láàrin àwọn ẹja àti àwọn ẹrànko mííràn.

Aristotle ló kọ́kọ́ ṣe àkíyèsí èyí nínú Ehoro, o rí pé, àwọn ọmọ Ehoro ni ìwọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ, èyí sì máá n mú kí àwọn ti o bá kẹ́rẹ́ lọ́jọ́ orí kéré ni ìwọ̀n náà.

Èyí túmọ̀ sí pé àsìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ ni ó ni oyún àwọn ọmọ náà wáyé.