Seyi Makinde ní rògbòdìyàn tó ń wáyé láàrí òun àti Fayose ti di ohun ìgbàgbé

Fayose son wedding

Oríṣun àwòrán, Olagunju Lekan

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti ke si awọn ọmọ Naijiria lati maṣe pa ara wọn nitori awọn oloṣelu.

Makinde lo sọ ọrọ naa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọkunrin gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose, eyii to waye niluu Eko.

Lara awọn oloṣelu to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa ni gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, to fi mọ gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Olagunsoye Oyinlola ati gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Segun Oni.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Makinde, Wike, Oyinlola, Oni ati Fayose, ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Fayemi.

Nigba to n sọrọ, Makinde ni ọrọ oṣelu kii ṣe ohun to yẹ ki eeyan fi ẹmi ara rẹ di.

O ṣalaye pe rogbodiyan to n waye laarin oun ati Fayose ti di ohun igbagbe.

Makinde ṣalaye pe yatọ si pe igbeyawo ọmọ Fayose mu irẹpọ wa laarin awọn oloṣelu, o ni awọn tọkọ-taya naa kii ṣe ẹlẹsin kan nitori ọkan ninu wọn jẹ Musulumi, nigbati ẹnikeji jẹ ọmọlẹyin Kristi.

Gomina ọhun sọ siwaju si pe ko yẹ ki awọn oloṣelu maa ṣe oṣelu ẹtanu, wọn si gbọdọ mọ pe ipo oṣelu kii ṣe agidi, paapaa bi eto idibo ọdun 2023 ṣe n sunmọle.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

O ni "Ọrọ oṣelu kii ṣe ohun to yẹ ki ẹmi eeyan maa lọ si, eto idibo gbogbogbo ti n sunmọle, mo si fẹ fi akoko yii parọwa si gbogbo awọn oloṣelu lati ṣe jẹjẹ."

"Ti ẹ ba wo igbeyawo yii daadaa, tọkọ-taya wa lati idile Musulumi ati Kristẹni, nitori naa, ki bogbo awọn to maa n ja lori ọrọ ẹsin tu inu wọn ro."

Makinde pari ọrọ rẹ pe "Ti ẹ ba wo awọn gomina ipinlẹ tẹlẹri wọnyii, Segun Oni, Ayo Fayose ati Kayode Fayemi, bo tilẹ jẹ pe wọn ti tukọ ipinlẹ Ekiti, wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa."

"Nitori naa, to ba ni ẹni to fẹ pa ara rẹ nitori awọn oloṣelu, ko tu ero inu rẹ pa."

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'