Akure kidnapping: Ajínigbé jí ọmọ ìyá méjì gbè nínú ọkọ̀ ìyá wọn nílùú Akure

Nigerian Police

Oríṣun àwòrán, ndtv

Awọn ajinigbe ti ji awọn ọmọdebinrin meji kan gbe lọ lakata iya wọn niluu Akure.

Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi aago mẹjọ aṣalẹ lagbegbe Leo lọjọ Ẹti.

Awọn ajinigbe ọhun kọlu iya awọn ọmọ naa lẹnu ọna ọgba ile wọn lasiko ti obinrin naa n ṣilẹkun abawọle, ko le wa ọkọ rẹ wọ inu ọgba ile ọhun.

Iroyin ni awọn ajinigbe naa gbe ọkọ ti wọn wa, ṣugbọn wọn gba kọkọrọ ọkọ iya awọn ọmọ naa, wọn si gbe ọkọ ọhun lọ lẹyin ti wọn fi ọkọ ti wọn gbe wa silẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Funmilayo Odunlami ti fidi iṣẹlẹ mulẹ fun awọn akọroyin niluu Akure.

Odunlami sọ pe wọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ awọn leti, awọn akọṣẹmọṣẹ ẹka to n ri si ọrọ ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa si ti bẹrẹ si n wa awọn ọmọdebinrin ọhun atawọn to ji wọn gbe lọ.

Ẹwẹ, ijinigbe tii n wọnpọ ni iha Iwọ Oorun Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii, bo tilẹ jẹ pe ikọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ṣiṣẹ takun-takun lori eto abo.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Loṣu to kọja, eeyan mejila to n rinrinajo ko sọwọ awọn ajinigbe lopopona Ifira-Akoko si Idoani.

Bẹẹ naa ni wọn tun ji alukọ fasiti Adekunle Ajasin kan gbe lọ ninu oṣu ti a wa yii loju ọna marosẹ Akure si Ado Ekiti.

Bakan naa ni awọn ajinigbe tun kọlu eeyan mẹrin ninu ẹbi kan naa.

Lara awọn eeyan naa ni baba, awọn ọmọ rẹ meji ati ẹnikan ninu mọlẹbi wọn wa lagbegbe Iju-Itaogbolu, ni ipinlẹ Ondo yii kan naa.

Àkọlé fídíò, Àwọn abirùn ọmọ tí òbí wọn tì mọ́lé ni mo lọ ń kó jáde láti máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ iléèwè - Sekinat Ahmed