Rosemary Ndlovu: Nítorí owó, ọlọ́pàá obìnrin kan pa mọ̀lẹ́bí rẹ̀ márùn-ún àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Ile ẹjọ ti sọ pe obinrin kan to jẹ ọlọpaa tẹlẹ, Nomia Rosemary Ndlovu jẹbi ẹsun pipa mọlẹbi rẹ marun-un ati ọrẹkunrin rẹ.
Laarin ọdun 2012 si 2018 lo pa awọn mẹfẹẹfa pẹlu iranlọwọ agbanipa.
Idi to si fi pa wọn ni pe ko le gba owó ti ileeṣẹ adojutofo ẹmi yoo san fun ẹbi ẹni to ba ku.
Nomia Ndlovu ti fi igba kan jẹ ọlọpaa orilẹ-ede South Africa.
Ọwọ pada tẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ọhun lẹyin to tun gbe agbanipa miran lati ba a pa aburo rẹ obinrin, lọ si ileeṣẹ ọlọpaa.
- Òṣèré Tíátà ṣèèṣì yìnbọn lórí ìtàgé, arábìnrin kan ti forí la ikú, òmìí farapa
- Ẹ fi ọkàn balẹ̀, a o ṣàfihàn gbogbo àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ Endsars - Babajide Sanwo-Olu
- 'Fídíò ẹ̀rí táa wò ṣàfihàn ibi tí Baba Ijesha ti ń rán ọmọ Princess létí bí òun ṣe fi ọwọ́ kàn án ní ọmọ ọdún méje'
- Wọ́n ní ìpànìyàn wáyé ní Lekki, àmọ́ a kò rí ẹ̀jẹ̀ tàbí òkú èèyàn kankan títí d'òní- Lai Mohammed
Bakan naa ni ile ẹjọ sọ pe Ndlovu tun jẹbi igbiyanju lati pa iya rẹ, Maria Mushwana, to si tun ṣe mago-mago owo lati ileeṣẹ adojutofo, lẹyin to ti ko 1.4m Rand ($95,000) owo orilẹ-ede South Africa sapo.
Lasiko igbẹjọ rẹ to waye fun oṣu mẹta, agbẹjọro ijọba ṣalaye pe niṣe ni Arabinrin Ndlovu ṣeto adojutofo fun awọn ẹbi rẹ ko to pa wọn.
Ibatan rẹ, Madala Homu, lo kọkọ pa ninu oṣu Kẹta, ọdun 2012.
Lẹyin naa lo pa aburo rẹ, ko to pa ọrẹkunrin rẹ, ati ọmọ aburo rẹ mẹta.
Oṣu Kinni, ọdun 2018, lo pa ẹni to pa kẹhin, Brilliant Mashego.
O ma n gba agbanipa ni fun awọn to ba fẹ pa, ṣugbọn lọdun 2013, fun'ra rẹ lo fun aburo rẹ Audrey Somisa Ndlovu, ni majele jẹ ko to fun un lọrun pa.
Opin de ba ipaniyan rẹ lẹyin to gbe iṣẹ fun ẹnikan lati tun ba a pa aburo rẹ miran ati ọmọ rẹ marun-un, ni oṣu Kẹta, ọdun 2018.
Ṣugbọn ọkunrin to gbe iṣẹ naa fun un sọ fun awọn ọlọpaa. Eyi si lo mu ki wọn o dẹ pakute fun, ti wọn fi ni akọsilẹ ohun rẹ bo ṣe n gbeero lati pa awọn ibatan rẹ naa.
Ninu fọnran ohùn naa ni wọn ti gbọ ti Ndlove n sọ bo ṣe fẹ ki wọn o dana sun awọn mẹfẹẹfa laaye ninu ile wọn, to si tun sọ pe "oun nilo owo ti oun yoo gba lori wọn".
O ti kọkọ sọ nile ẹjọ pe oun ko jẹbi, to si ni irọ ni awọn aadọta ẹlẹri ijọba n pa mọ ọ.
Ṣugbọn agbẹjọro ijọba, Riana Williams, ṣafihan awọn ẹri to fi ibaṣepọ rẹ han pẹlu ọpọlọpọ awọn to pa ṣaaju iku wọn, ati anfaani to jẹ lẹyin rẹ.
Ẹri fihan pe Ndlovu lo ṣaba ma n ri wọn kẹhin ki wọn o to ku, tabi ko jẹ ẹni akọkọ to ṣakiyesi pe wọn di awati.
"Orukọ ara rẹ lo fi silẹ ninu iwe adojutofo gẹgẹ bi ẹni ti yoo jogun, ko le ba ri owo lori owo adojutofo ẹni to ku, ati owo isinku."
Oṣu to n bọ ni wọn o ṣe idajọ rẹ nile ẹjọ.
















