Akinwumi Farooq Akewi: Yàtọ̀ fún títayọ mi nínú ewì, mo fẹ́ dàgbà di Ajobiewe àti Wole Soyinka

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Akinwumi Farooq ko ju ọmọ ọdun mẹtala lọ to si wa kilaasi kẹrin nileewe alakọbẹrẹ.

Farooq fi ifẹ han si ewi kike lati kekere ti inu rẹ si maa n dun lati lọ jokoo si ẹgbẹ awọn agbalagba kan to maa n kewi nigba to ṣi wa ni ọmọ ọdun mẹjọ.

To ba ti de ile a tun fi gbogbo alẹ maa tun awọn owe to gbọ ka.

Akinwumi yan lati fi ewi ki alejo pataki kan ni ile ẹkọ rẹ ku abọ ni arakunrin ọhun, Ogogo ba yaa bo ṣe n kewi lo ba gbee sori ayelujara, ibẹ ni iyi Akinwumi ti bẹrẹ.

O ti wa di gbajugbaja lẹyin igba ti arakunrin Ogogo gbe fidio rẹ sori ayelujara ti ọpọ eeyan si wo o.

Ilu Ilaro ni ipinlẹ Ogun ni Akinwumi wa ko to di pe gbajumọ akewi mii to n jẹ Remmy Chanter muu lọ si ilu Eko to si di oloore rẹ titi di oni. Koda to n ran an lọ si ile ẹkọ yatọ fun pe o n kọ ọ lawọ nkan ti ko mọ ninu ewi.

Nigbakuugba ti Akinwumi o ba si ni ileewe, o maa n lọ si awọn inawo lati fi ẹbun rẹ han.

Afojusun ọmọdekunrin yii ni lati dagba ko di ẹni iyi bii Ọjọgbọn Wole Soyinka.