Adigun Olowe Yoruba Proverbs: Israel Adebayo tó ń pa òwe Yorùbá ọgbọ̀n lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo
"Igba ti baba mi wa laye, wọn fẹran ki wọn maa fi owe sọrọ, o da bii pe ẹbun ọmọwe lo sọ̀kalẹ̀ latori baba mi sori emi to si bọ sori ọmọ mi"
Adebayo Olamilekan Israel ni orukọ abisọ rẹ ṣugbọn ti gbogbo eniyan mọ ọ si Adigun Olowe Yoruba.
Baba rẹ, Adebayo Oladimeji Ishola ni lati kekere ti awọn ti bi ọmọ naa lo ti maa n ṣe awọn nkan awoṣi ẹnu silẹ eyi to si mu ki iya iya rẹ fun un ni alajẹ "Ara".
Ọmọ meji ni wọn ti bi ṣaaju Adigun Olowe Yoruba ti wọn bi nigba to pe ọdun kan geerege ti ọmọ ti wọn bi ṣaaju rẹ ku.
"Tẹẹ ba tun ni ko gbe iwe ti ileewe rẹ jade, yoo ya yin lẹnu".
Baba rẹ ni o rọrun fun oun gan lati yi ọrọ gẹẹsi pada si ede Yoruba eyi ti ọmọ rẹ naa yan laayo.
O ni ọjọ kan lo kọkọ bẹrẹ rẹ tawọn ṣaadede ri i to tun ọrọ ti oun sọ lede Yoruba ati gẹẹ́si sọ papọ lẹẹkan ṣoṣo titi to fi dori pe o lee sọ owe ọgbọ̀n ati itumọ rẹ lede gẹẹ́si.