Nollywood: Kìí ṣe nǹkan ìtìjú pé èmi ni mò ń gbọ́ bùkátà ẹbí mi - Nkechi Blessing

Nollywood: kìí ṣe nǹkan ìtìjú pé èmi ni mo ń gbọ́ bùkátà ẹbí mi- Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, Nkechi

Gbájúgbajà òṣèré Nollywood Yoruba Nkechi Blessing Falegan pe kò sí ǹǹkan ìtìjú fún òun láti jẹ́ ẹni to n gbọ́ bùkátà àwọn ẹbi òhun.

Ojú òpó Insagram rẹ ló ti fi ìdí ọ̀rọ̀ yìo múlẹ̀ lásìkò tó n ṣe ìránti oṣù kan ti ìyá rẹ re ibi àgbà n re.

Gbajúgbajà òṣèré náà pàdánù ìyá rẹ lẹ́yín ọjọ́ díẹ̀ sí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, tí ó sì ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún ìyá rẹ ni ọ̀eẹ̀ tó kọjá.

Nollywood: kìí ṣe nǹkan ìtìjú pé èmi ni mo ń gbọ́ bùkátà ẹbí mi- Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing

Lẹ́yìn ayẹyẹ ọkú náà ni òṣèré ọhún lọ sí ilẹ Gẹ̀ẹ́sì láti lọ bá ọkọ rẹ David Adelegan tí kò sí nibi ayẹyẹ ìsìnku ìyá Nkechi Blessing.

Ó ṣàlàyé pé, ìyá òun àti ẹbi tí òin nílò láti gba bùkàta wọn ó fàá tí òun fi n ṣe iṣẹ àṣefẹ́ẹ̀kú, kìí ṣi ṣe ohun ìtìjú rárá.

Ní báyìí òṣeré náà ni òun ṣeetan láti padà sí ẹnu isẹ́ àti láti tẹ̀síwájú lẹ́nu iṣẹ́.

Nkechi Blessing dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ènìyàn tó dúró tìí lásìkò ìsìnkú ìyá rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi