Sunday Igboho news: Èmi ò rán alátẹnujẹ olóṣèlú tàbí ajagunfẹ̀yìntì kankan láti lọ bẹ Buhari Sunday Igboho pariwo síta

Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday adeyemo/instagram

Eekan ọmọ Yoruba to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti pariwo sita pe oun ko ran ẹnikẹni niṣẹ lati maa lọ bẹ Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari tabi ijọba apapọ lorukọ oun.

Sunday Igboho ṣalaye pe awọn agbẹjọro oun nikan loun fi ọrọ si lẹnu lorukọ oun nibikibi tabi nigbakugba.

Ọrọ yii jẹyọ ninu atẹjade kan eyi ti ileeṣẹ amofin Yọmi Alliyu SAN to jẹ agbẹjọro fun oloye Sunday Igboho fi sita.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Atẹjade naa fi kun un pe Sunday Igboho ko ran oloṣelu kankan to n yapa lati ẹgbẹ oṣlu kan lọ si omiran , tabi ajagunfẹyinti kankan niṣẹ lati lọ maa gbẹnu sọrọ fun oun.

"A rii gbọ pe awọn oloṣelu kan ti n ko girigiri bo onibara wa, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti inagijẹ rẹ n jẹ Igboho Ooṣa ati iyawo rẹ, Arabinrin Rọpo Adeyẹmọ lorilẹede yii ati nilu Cotonou lati fun wọn laṣẹ lati ls si ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ọna lati wa atilẹyin fun ifẹ tuntun ti wọn ri ati iyapa wọn lọ si ẹgbẹ oṣelu APC lsna ati le lọ woju rere awọn to wa nipo"

Atẹjade naa tun ṣalaye rẹ ni kikun pe Sunday Igboho ko si fun ẹgbẹ oṣelu kankan bẹẹni ko si ni ifẹ tabi ikorira fun ẹgbẹ oṣelu kankan pẹlu nitori gbogbo awọn ololufẹ rẹ ko ms lẹgbẹ oṣelu tabi ilu kan.

Àkọlé fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou

"Ṣugbọn gbogbo awọn gomina ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa lẹkun iwọ orun gusu Naijiria lo bọwọ fun gẹgẹ bi aṣoju tootọ fun iran Yoruba"

O ni o ṣeni laanu pe oloṣelu kan ti orukọ rẹ ti di atẹmẹrẹ ti ko si ni ariwisi rere laarin iran Yoruba, pẹlu oṣiṣẹ abo kan to ti fẹyinti lee maa ko girigiri bo Igboho ati iyawo rẹ lati fun awọn laṣẹ ki wọn le lo awọn ọdọ ilẹ Yoruba ati ileeṣẹ aarẹ lai wo bi wọn ṣe fi eekan ọmọ Yoruba naa sẹwọn lọna aitọ lorilẹede Benin Republic.