Sunday Igboho's aides: Lady K àti Jamiu Noah, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi
Ibi ti a ti n wa huru-huru la tii ri hara-hara. Iroyin awọn to n ṣonigbọwọ Oloye Sunday Igboho ṣẹ ti ọwọ ijọba jade tan ni omii nipa rẹ tun gun lee.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe Babatunde Abibat ti ọpọ mọ si Lady K to jẹ obinrin kan ṣoṣo ti ajọ DSS ko pọ mọ awọn ti wọn ko nilee ajijagbara Yoruba Nation, Sunday Adeyemọ ti gba itusilẹ bayii pẹlu ọkunrin kan ti wọn jọ wa lahamọ, Jamiu Noah Oyetunji.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti orilede Naijiria pẹlu aṣẹ ijọba apapọ lọ ṣe ikọlu si ile ti Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho tabi Igboho Ooṣa ni Ọjọ Kini Oṣu Keje ọdun 2021 ni agbegbe Soka ni ilu Ibadan, ipinlẹ Oyo.
Iroyin gbode kan pe ẹmi awọn eeyan nu sii bẹ ti awọn idile wọn si n ṣọfọ bo tilẹ jẹ pe ijọba ni irọ ni.

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi
Loru ọganjọ kan naa ti wọn ṣe ikọlu sile Igboho ni wọn fi panpẹ mu gbogbo awọn amugbalẹgbẹ rẹ ti wọn ba ninu ile rẹ amọ ti wọn ko ba Igboho gangan nile.
Lati igba naa ni wọn ti n da ẹjọ awọn ọhun niluu Abuja, wọn tun lara wọn silẹ laipẹ amọ wọn kọ lati tu obinrin kan ṣoṣo to wa laarin wọn, Lady K ati ọkunrin kan Noah silẹ.
Nibayii, atẹjade ti ọkan lara awọn agbẹjọro fun ẹjọ to ba kan Sunday Igboho lorilede Naijiria, Pelumi Olajengbesi fi sita fihan pe wọn ti tu awọn meji to ku ni ahamọ DSS silẹ ni ọjọ Ẹti ọjọ kejilelogun oṣu Kẹwa ọdun 2021.
"Niwọn igba ti ọrọ ṣi wa labẹ iwadii, a o ni le sọ ohunkohun to ju eyi lọ". Agbẹjọro, Pelumi Olajengbesi fi ṣọwọ si BBC Yoruba.

















