Sekinat Ahmed: Àwọn ọrẹ binu si mi nígbà ti mo kọkọ bẹrẹ iléèwè àwọn ọmọ tó ní ìpèníjà ara

Àkọlé fídíò, Àwọn abirùn ọmọ tí òbí wọn tì mọ́lé ni mo lọ ń kó jáde láti máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ iléèwè - Sekinat Ahmed

"Ọmọ kan wa nibi lara awọn to ni ipenija ara ti wọn ti pa ti lati igba ti wọn ti muu wa ti iya rẹ naa tẹle wa, ẹẹkan ṣoṣo lo ti wa woo lati igba naa".

Kikọ ọmọde kii ṣe ohun teeyan n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ka to wa sọ pe kikọ awọn ọmọde to ni ipenija ara bii oju fifọ, rirọ lapa rọ lẹlẹ, ọmọ ti ọpọlọ rẹ ko ji pepe to ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Sekinat sọ iriri rẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba ati iru idẹyẹsi to ri lawujọ nigba to kọkọ bẹrẹ.

Eleyi gan ni arabinrin Sekinat Ahmed yan laayo to ti si wa di iṣẹ oojọ rẹ to n ṣe bo tilẹ jẹ pe ko mọ pe yoo di ipa ọna nla mọ oun lọwọ bayii.

Ileewe awọn akanda

Ile yii to tun jẹ ile iwe wa fun awọn ọmọde to ni ipenija ẹya ara loriṣiriṣi, o wa ni ipinlẹ Oyo.

Sekinat Ahmed kọ nipa imọ ẹkọ ara ọtọ ni fasiti to si kọkọ woye pe ki oun pari fasiti ki oun naa gbọn paali oun lati wa iṣẹ to dara lọ bi awọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Ẹwẹ,Sekinat pada di ẹni to n ṣe agbatẹru ile kan fun awn ọmọde ti wọn ti di apati nitori ipenija ara ti wọn ni.

"Mo ṣaa n ṣe temi ni ọna ti mo mọ lati maa ṣe iranwọ tori eeyan o mọ eyi teeyan o ṣe ti Ọlọrun yoo fi da eeyan lare".

Ileewe awọn akanda

"Mo ti gba ọmọ ti oju rẹ fọ lọwọ iya rẹ ti ẹsẹ si n dun iya ọhun to tun n sọ fun mi pe ọmọ mii ti oun bi ko si owo lati tọju rẹ, mo ni lati fun un lowo".

O ni a wọn ọrẹ oun binu si "nígbà ti mo kọkọ bẹrẹ iléèwè àwọn ọmọ tó ní ìpèníjà ara, wọn ní ẹni tó bá ti tóo tán ló máa ń ṣe irú ẹ.

Tí ǹkan bá dá tí mo bá tilẹ tọrọ ìrànwọ abọ “rice” lọwọ ọrẹ, wọn á ní ṣebí èmi ni mo pe ara mi".

Sekinat ni ọpẹlọpẹ ọkọ oun ati iya oun ti ọrọ tiwọn maa n mu inu oun dun lati ṣe iranwọ fun awọn ọmọde akanda yii.