Tradomedical Doctor Oluseyi Atanda: Báyìí ni mo ṣe ń fi ìṣègùn òyìnbó àti ti ìbílẹ̀ tọ́jú
"Baa ṣe n dagba taa n kọ iwe ti oyinbo lọ ni Fasiti naa la n kọ ti ifa ninu ile. Àwọn kan ṣaa lo ti n ṣe iwosan ki Dokita o to de aye".
Dokita onimọ nipa ẹya ara obinrin ati bi wọn ṣe n loyun, bimọ ti oloyinbo n pe ni Consultant Gynaecologist ni Dokita Oluseyi Atanda lo ba tun bu iyalẹnu kun iṣẹ imọ iṣegun oyinbo to n ṣe nipa fifi ẹsẹ ile tọọ, oun naa si ni adifa ti yoo baa yin fi ẹsẹ ile tọ ọ bi ẹ ba nifẹ sii.
Oluseyi ba BBC Yoruba sọ nipa bo ṣe n ko imọ iṣegun mejeeji yii pọ. Bo ba ṣee ni ti oyinbo ti ko jẹ, a si ti ẹsẹ ile bọ ọ boya ifa yoo jẹ.
Ile iwosan ti ileewe giga Ladoke Akintola lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ Dokita, ilee rẹ lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii Babalawo koda o tun gboye ninu imọ iṣegun iobilẹ - oun ni Ajana Awo ti ilu Osogbo to si tun jẹ Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣegun ibilẹ lapapọ nipinlẹ Osun.

