Myth of Witchcraft: Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

Àkọlé fídíò, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

Mọ̀ síi nípa bí Babalawo ṣe ń rán Esu níṣẹ́ nítorí ìṣòro àwọn Ẹ̀dá láyé- Abiodun Fatomilola

Kikọ ni mimọ ni ọrọ ile aye.

O yẹ ki eeyan maa wa imọ kun imọ ni.

Ipa Aje ati Babalawo

Oríṣun àwòrán, others

Abiodun Fatomilola mẹnuba ipo ti Olodumare fi awọn alagbara aye si ati bi o ṣe n lo awọn ẹlẹyẹ lori awọn eeyan gẹgẹ bii paṣan ati gẹgẹ bii ọna lati ṣoriire lawujọ.

Esu

Oríṣun àwòrán, Others

Oloye Abiodun Fatomilola ogbontarigi olukọ ninu ere itage, Ifa ati aṣa Yoruba ba BBc sọrọ lori pataki nini imọ nipa Ifa ti ko nii ṣe pẹlu ẹsin.

O sọ nipa ajọṣepọ to wa laarin awọn Eleye, Babalawo ati eeyan nile aye.

Ati pe ibi gbogbo lati n ko adiyẹ alẹ ni ọrọ awọn ajẹ jẹ lai yọ awọn orilẹ-ede bii China ati Japan silẹ.

Ifa

Oríṣun àwòrán, others

Abiodun Fatomilola tun sọ ipo ti Ifa wa gẹgẹ bi imọ fun ẹda.

O ni Ifa ni ilana imọ kii ṣe ẹsin rara.

Ati pe iyatọ wa laarin Adahunse, Babalawo, Onisegun ati Onifa.

Fatomilola

Bakan na lo sọ nipa bi wọn ṣe wọ inu ara wọn.

O ni gbogbo Oriṣa kọ ni ibọ ṣugbọn gbogbo ibọ ni Oriṣa.

Fatomilola ni Orunmila nikan ni ko ni iboji oku ninu awọn oriṣa nitori pẹ ẹyẹ Asa idi lo gbe Orunmila pada si ọrun to kọ awọn eeyan ni Ifa lati ni imọ lori ọna abayọ si iṣoro wọn.