2022 budget: Buhari gbá àbá owó ìsúná ₦16.39 trn lọ sí ilé aṣòfin

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad/facebook
Apapọ owo ti ijọba nireti pe yoo wọle si ni apo lọdun 2022 jẹ 17.70 Trillion Naira.
Aarẹ Muhammadu Buhari lo sọ eyi lasiko to gbe aba eto isuna ọdun 2022 lọ sile aṣofin nilu Abuja.Òní ni Ààrẹ yóò kéde ètò ìṣúná ọdún 2022
Buhari sọ pe akọle owo eto isuna naa ni "Isuna fun idagbasoke ati iduroṣinṣin ọrọ aje.
O ṣalaye pe aba isuna naa to jẹ odindi isuna to kẹhin lati ọwọ ijọba oun ni wsn ṣe agbekalẹ rẹ lati le tẹsiwaju pẹlu aṣeyọri isuna to kọja.
- Àjọ WHO gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára àìsàn ibà jáde fún ilẹ̀ Afrika
- Àwọn adari ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ ṣèpàdé lórí ọjọ́ ọ̀la ẹgbẹ́ náà
- Tọkọ-taya kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán ní Ọjọ́ Àyájọ́ Ọ̀mìnira Nàíjíríà
- Ọjọ́ iwájú ní kí o wò, má fi gbèsè owóyàá bá ọjọ́ ọlá àwa ọmọ Nàìjíríà jẹ́-ẹgbẹ́ MAN
- Àpẹ́rẹ́ àìsàn tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ pọ̀ lára àwọn obinrin tó wà ní ìlú Ibadan - Ìwádìí fìhàn
O ni owo yiya to to 5.01 trillion Naira ni gboogi ti awọn yoo fi gbọ bukaata owo isuna naa, pẹlu 90.73 lati ara awọn dukia ijọba ti wọn ba sọ di ti aladani, ati 1.16 Trillion Naira lori awọn owo ti wọn ya fun awọn akanṣe iṣẹ kan.
Aarẹ Buhari sọ pe lootọ ni ko si nkan to buru ninu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n kọminu lori owo ti ijọba n ya, o ni ṣugbọn "igbagbọ wa ni pe gbese ti a jẹ ko ti i kọja nkan ti agbara wa le ka".
O ṣalaye pe ọpẹlọpọ awọn owo ti ijọba ya lo fi doola ọrọ aje to dẹnu kọlẹ lẹẹmeji lati igba ti iṣejọba oun ti wa nipo.
AWỌN IRETI NKAN TO ṢEEṢE KO ṢẸLẸ
a.Tita agba eporọbi kan ni Dọla mẹtadinlaadọta
b.Ipese eporọbi to to 1.88 miliọnu àgbá lojoojumọ.
c.Dọla kan si N410.15
d.Idagbasoke awọn nkan ti wọn n ṣe ni Nairajia pẹlu ida 4.2, ati ida mẹtala afikun si bi nkan ṣe wọn si.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yan ẹ̀ní tó tí bẹ̀rẹ̀ iléẹ̀kọ́ kí wọ́n tó bíi sáyé gẹ̀gẹ̀ bí ọmọ ìgbìmọ̀ Àjọ EFCC
Gbogbo owo ti ijọba apapọ nireti pe yoo wọle si apo rẹ ni 12.72 trillion Naira, amọ owo to ni lọwọ lati fi gbọ bukaata isuna ọdun 2022 ko ju 10.13 lọ.
Awọn owo naa jẹ eyi to ri lara iranwọ, ati ileeṣẹ mẹtalelọgọta ti ijọba ni.
Owo ti ireti wa pe yoo wọle lara eporọbi ni 3.16 trillion, owo ori 2.13 trillion Naira ati awọn owo mii to jẹ 1.82 trillion Naira.
AWỌN NKAN TI YOO JẸ KOKO LỌDUN 2022
a. Wiwa ọna miran ti owo yoo ma gba wọle yatọ si eporọbi, ati idagbasoke fun ẹka awọn olokoowo kekeeke
b. Ninawo le awọn nkan amayedẹrun to ṣe koko
c. Riro eto aabo lagbara
d. Ṣiṣe igbelarugẹ eto ilera ati ẹkọ
e. Adinku si òṣì
f. Adinku si idẹyẹsi ni ẹkùn kọọkan, ọrọ aje ati igbeaye ojoojumọ
AWON NKAN TI IJỌBA YOO NA OWO LE LORI NI 2022
a.Owo bukaata ti ayipada ko le ba fun awọn ẹka ati ileeṣẹ ijọba kan - 768.28 billion Naira
b. Bukaata ti ki ṣe fun gbese sisan - 6.83 trillion
c. Owo awọn oṣiṣẹ - 4.11 trillion Naira
d. Owo ifẹhinti ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ to fẹhinti - 577.0 billion Naira
e. Owo fun awọn inawo pẹẹpẹpẹ ninu iṣejọba - 792.39 billion Naira
f. Akanṣe iṣẹ - 5.35 trillion Naira
g. Gbese sisan - 3.61 trillion Naira
h. Owo ti yoo ya sọtọ fun lilo lori gbese idokoowo - 292.71 billion Naira
Aarẹ Muhammadu Buhari gbe aba isuna 2022 lọ si ile aṣofin
Oni, ọjọ keje, oṣù Kẹwaa, ọdún 2021 ni Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe agbekalẹ eto ìṣúná ọdún 2022 níwájú àpapọ ile igbimọ aṣofin Naijiria.
Igbakeji Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Ovie Omo-Agege, lo fi ọrọ náà lede lọjọ Ìṣẹgun.
Omo-Agege sọ niwaju ile náà pé Ààrẹ kọ lẹta si oun ṣaaju nipa eto ìṣúná náà.
O ni Ààrẹ sọ ninu lẹta ọhun pe oun yóò ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣúná náà tó ti fi ranṣẹ ṣaaju.
- Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ ṣóra fún ''Frozen Turkey, Chicken'' àwọn ìkà ń fí ''Formalin'' sí i- NAFDAC
- Irú àìsàn wo ló ń bá Sunday Igboho finra ní Benin kí sì ní àwọn àgbààgbà Yorùbá n sọ sí ọ́rọ́ yi?
- Ìyàwó Ganduje ti kúrò lọ́dọ̀ọ́ EFCC, wo ohun tó gbé e lọ síbẹ̀....
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé tó máa n dibọn bí dírẹ́bà láti jí àwọn arìnrìnàjò gbé
- Ìdí rè é. tí ọmọ tí kò bá tí pé 18 kò ṣe lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
Ààrẹ ni ki ile ọhun buwọ́lù àtúnṣe naa ni ìbámu pẹlu ofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe, èyítí o rọ mọ ọrọ epo bentiro.
Wọn ti wa fi lẹta Ààrẹ náà ṣọwọ sí igbimọ to n ri sí ọrọ ètò ìṣúná nílé ọhun.
Omo-Agege sọ fún igbimọ náà ko tètè ṣiṣẹ lori lẹta Ààrẹ náà ni kankan ko si jabọ fún ile laipẹ.
O ni "Igbimọ yii ni lati tete ṣiṣẹ lórí lẹta náà ko si jabọ pada ki Ààrẹ to kéde eto ìṣúná tuntun lọjọbọ.
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila náà kede ohun kan naa níwájú ilé tirẹ to n dari.
Ṣaaju ni ile igbimọ aṣofin ti kọkọ buwọ́lù owo ti iye rẹ tó ₦13.98 tiriliọnu gẹgẹ bíi eto ìṣúná ọdún 2022 ti Ààrẹ Muhammadu Buhari fi ranṣẹ sí wọn.
- Obìnrin mẹ́rin ni igi Ọdán wó pa ni Oyo kó tó tún dìde padà- Eni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú ẹ
- Ìyàwó Ganduje ti kúrò lọ́dọ̀ọ́ EFCC, wo ohun tó gbé e lọ síbẹ̀....
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé tó máa n dibọn bí dírẹ́bà láti jí àwọn arìnrìnàjò gbé
- Ìdí rè é. tí ọmọ tí kò bá tí pé 18 kò ṣe lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
- Bí ẹnu rẹ bá ń rùn, ọ̀nà márùn-ún tí o lè gbà láti ṣẹ́gun ẹnu rírùn àti ìṣòrò eyín


















