NAFDAC: Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ ṣóra fún ''Frozen Turkey, chicken'' àwọn ìkà ń fí ''Formalin'' sí i kó lè pẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati ounjẹ lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun jijẹ adiyẹ tutu ti wọn n gbe si inu yinyin paapaa lati oke okun.
Ajọ NAFDAC ni awọn ika eniyan to n ta awọn adiye tutu ti wọn n gbe si inu yinyin yii lẹyin ti wọn ba ti fi ''formalin'' si inu rẹ.
Agbẹnusọ Ajọ NAFDAC, Dokita Abubakar Jimoh gba awọn Naijiria ni iyanju yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori ijamba ati ewu ti awọn ounjẹ inu yinyin yii n da si ara awọn eniyan.
- Èkó àti Rivers nìkan kọ, wo àwọn ìpínlẹ̀ Gúúsù-Gúúsù mi tó ṣetán láti lọ sílé ẹjọ́ gíga jùlọ lórí VAT
- À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah
- Nkechi Blessing sọ̀rọ̀ nípa ikú ìyá rẹ̀, ó tún tú àṣírí kàbìtì nípa ìhùwàsí ara rẹ̀ táyé kò mọ̀
- Kìí ṣe pé ìjọba ń fi ọwọ́ jẹ́jẹ́ mú àwọn jàndùkú o - Lai Mohammed
Jimoh ni awọn ọlọja okunkun yii n fi formalin si inu awọn adiyẹ yii ki o ma le dabi tuntun ti wọn ṣẹṣẹ pa fun ọpọlọpọ ọjọ.
''Formalin ma n jẹ ki awọn ounjẹ yii dabi tuntun fin bii ọṣẹ melo ti wọn yoo fi ta a fun awọn araalu.''
''Amọ jijẹ ounjẹ ti wọn fi formalin gbe pamọ le e ṣe akoba fun agọ ara eniyan.''
''NAFDAC n pe akiyesi awọn ọmọ Naijiria si iwa buruku yii nitori awọn eniyan yii n gbe awọn ounjẹ yii wọle lẹyin ti ijọba apapọ ti fi ofin de.''
- Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere
- Ọjọ́ burúkú èṣù gbomimú ní Ọyọ! igi ńlá wó pa ọ̀pọ̀ ènìyàn
- Irọ́ ni, kò sóhun tó jọ pé a fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé owó 'domiciliary account' àwọn ènìyàn Nàìjíríà- CBN
- Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan rọ Báàlẹ̀ Lagelu Abọke kúrò lóyè lórí ẹ̀sùn aṣemáṣe
- Ṣé lóòótọ́ ní pé EFCC mú ìyàwó Gómìnà Ganduje ìpínlẹ̀ Kano?
Bakan naa lo fikun un pe tita awọn ọja yii ko ni jẹ ki awọn to n ta adiyẹ ati awọn ohun ọṣin labẹle moribọ.
Formalin ni wọn fi ma n gbe awọn oku pamọ ni ile igbokusi ki o ma ba a run, ti wọn ba si fi si ounjẹ awọn eniyan, o le e fa aisan jẹjẹrẹ ẹjẹ fun awọn eniyan ati awọn aisan miran.














