Nkechi Blessing sọ̀rọ̀ nípa ikú ìyá rẹ̀, ó tún tú àṣírí kàbìtì nípa ìhùwàsí ara rẹ̀ táyé kò mọ̀

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing
Gbajugbaja Òṣeré fíìmù Yorùbá yii Nkechi Blessing jẹ oṣere kan ti ẹnu kò ṣi lára rẹ.
Laipẹ yii ni ṣáájú iku iya rẹ àmọ́ pẹlu gbogbo eyi náà Nkechi kọ lati gba ọjẹgẹ, ṣe lo sì ń mókè ninu isẹ rẹ to sì ti di ólórúkọ ńlá laarin awọn akẹgbẹ rẹ bo tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ẹ̀yà Igbo ni.
Iroyin tilẹ̀ sọ pe ko fi iya rẹ ṣeré rara kódà títí di ìgbà ikú rẹ inú ilé Nkechi lo n gbe.
Ó fi hànde pé irẹpọ to wa laarin oun ati iya rẹ to bẹẹ to sọ ní gbangba pe iya òun ni igi lẹyin ọgba oun.
Nkechi sọ nigba kan ri pe bi òun bá padanu ìyá òun nìkan ni ohun tó lè mú òun sọkún lai tilẹ̀ mọ pe ọlọ́jọ́ ti ń kan ilẹkun.
Afi tí iku sì de ni ọjọ kẹtalelogun oṣù Kẹ̀sán ọdun 2021 tí màmá Gloria Obasi Sunday ti wọn n pe ni Mummy Nkechi dagbere faye.
- A pàdánù Ìyá Nkechi Blessing láìpẹ yìí- Toyin Abraham
- Ìkébé mi tóbí ju ohun tí mo lè dọwọ́ bò lọ, n kìí fí ṣakọ- Nkechi Blessing
- Ṣé lóòtọ́ ni Nkechi Blessing ṣe ìgbéyàwó?
- Nkechi Blessing àti Bobrisky fìjà pẹ́ẹ́ta nítori ọ̀rọ̀ "Tattoo"
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
"Ẹni ọdun méjìlélógún ni mi mo dẹ sì ń gbé pẹlu ìyá mi. Torí tìrẹ gan ni mí ó ṣe tíì kò lọ bá ọkọ mi, mo sunmọ ìyá mi gidi gan mi ò sì lè fi silẹ. Kí n tó fún ẹ ní mílíọ̀nù kan, máa tí fún ìyá mi ni mílíọ̀nù marun-un.
Nkechi sọ lẹyin iku iya rẹ pé "kani àwọn dókítà béèrè owó láti doola ẹ̀mí rẹ, òun a bẹ gbogbo ayé láti ran òun lọwọ.
Nkechi ni inu rirun lásán ni ìyá òun ni ó ṣe òun. "Nkan to gbẹ̀yìn ti mo gbọ́ nìyẹn o".
Nkechi sọ pupọ nípa ìyá rẹ àti bó ṣe fi igboya tọ ọ dàgbà.
Kí ni Nkechi sọ nípa idile rẹ?
Nkechi ni òun ó lè fi gbigbajumo bọ ẹbi oun. "Ẹ gba gbigbajumo yín kẹẹ fi ẹbi mi silẹ.
Mi ò lè jẹ akuṣẹ Òṣeré láyé. Mo fẹ́ kí n lè tọ́ka si ọkọ kan pé owó isẹ mi ni mo fi raa".
Nkechi ni awọn osere akẹgbẹ awọn elédè gẹ̀ẹ́sì ń pá owó gidi gan àti pé oogun wọn ni wọn ń lọ tẹẹ bá rí wọn tí wọ́n ń ra gbogbo nkan.
Nkechi jẹ ko di mimọ pe àwọn eeyan ńlá ńlá lo ko owo sínú fíìmù gẹgẹ bii onigbọwọ.
Ó fi wọn we fiimu Yoruba to ni eeyan kan lè dédé yà wọle kò dẹ máa kopa ninu ere.
"Mo leè sọ awọn eeyan fún yín nínú fíìmù Gẹ̀ẹ́sì tí wọn kò gbé ère ara wọn jáde ri ti wọn si n kore owó gidi gan. Oludokoowo láwọn to n ṣe fíìmù Gẹ̀ẹ́sì torinaa ni wọn ṣe ń kore owó gidi gan.
Nínú iforowanilenuwo kan tó ṣe ló ti sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi dá sí ọrọ Baba Ijesa èyí tó mú ki wọn dáa dúró laarin awọn osere TAMPAN.
- À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah
- Kìí ṣe pé ìjọba ń fi ọwọ́ jẹ́jẹ́ mú àwọn jàndùkú o - Lai Mohammed
- Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan rọ Báàlẹ̀ Lagelu Abọke kúrò lóyè lórí ẹ̀sùn aṣemáṣe
- Ṣé Facebook, Instagram, WhatsApp ti yín náà ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé...
- Ẹ yé kóra jọ pọ̀ láti d'ẹ́rù ba ni pé ọwọ́ Yorùbá ni Ààrẹ 2023 gbọ́dọ̀ bọ́ sí- Shekarau
Ó ní òun ó lè sọ pé wọn fipa bá òun lopọ rí àmọ́ ó sún mọ́ ọn.
"Pé ẹ lè mi kúrò lagbo TAMPAN gaan tún jẹ́ ọna lati ran mi lọwọ".
Wọn ní kilode to máa ń jà lórí ayélujára, ó ní "ẹ o le bu mi ki n dakẹ. "Ẹ jẹ ki n yà yín lẹ́nu, èmi àti ọkọ mi ò kí n ṣe ọrẹ ara wa lori Instagram.
Ó lè di ọjọ kan ka ni ìjà lórí Whatssap taa tí ń sọ̀rọ̀ lojoojumo kí n dẹ lọ yọ ọ kuro lára àwọn ọrẹ mi lórí Instagram.
tí àwọn oniroyin ayelujara yóò ti lọ gbé e èyí sì lè tún bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ irẹpọ jẹ.
Nkechi fi kún un pé inú òun dùn pẹlu bí òun ṣe ń ṣe nkan òun fún àpẹrẹ "mo ṣe ìgbéyàwó kò sì sí ẹni tó mọ sii. Inú mi dùn gidi gan pelu igbe ayé mi mo sì ń ṣe fàájì".






















