IPOB Sit at Home: Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ ajijagbara to n pe fun Biafra Nation, IPOB ti kesi awọn ọmọ Yoruba ati gbungun Naijiria lati darapọ mọ ifẹhọnuhan awọn lati tako ijọba Naijiria lori atimọle Nnamdi Kanu.
Ẹgbẹ IPOB ni awọn n ṣe ifẹhọnuhan nipa jijoko si ile lọna ati gbe wa si ileẹjọ ni Ọjọ Kọkanlelogun, Osu Kẹwaa, ọdun 2021.
IPOB ni aṣẹ ti awọn pa fun awọn eniyan lati joko sile fun oṣu kan ni lati ṣe atilẹyin fun Nnamdi Kanu to wa ni apanpẹ ajọ DSS.
- Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ IPOB, Emma Powerful fi lede lo ti kesi gbogbo awọn oniṣowo to jẹ ẹya Igbo ni ile ni oko lati ti ileeṣẹ wọn fun oṣu kan lọna ati ṣe atilẹyin fun Kanu.
''Awa ẹgbẹ IPOB n kesi awọn ekeji wa to n ja fun ominira ilẹ Yoruba ati awn to wa ni gbungun Naijiria lati darapọ mọ wa fun osu kan lai lọ si ibi iṣẹ gẹgẹ bi atilẹyin fun olori wa, Nnamdi Kanui.''
''Gbogbo ẹyin ololufẹ Biafra ni ile ni oko to fi mọ awọn ẹlẹsin Kristeni to wa iha Ariwa orilẹede Naijiria, amọ ti ijọba Naijiria n fi iya jẹ, ẹ darapọ mọ wa ki a jọ satilẹyin fun Nnamdi Kanu.''
''Iya ati iṣẹ ti awọn Fulani ọdaran darandaran fi n jẹ awọn eniyan ti to gẹ, to fi mọ ipaniyan ati ifiyajẹni ni ọna aitọ.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Asiko ti to lati jẹ ki ijọba ati awọn Fulani darandaran yii mọ wi pe a kii ṣe atẹmẹrẹ, ki wọn ye e fi iya jẹ wa mọ.''
''A parọwa si gbogbo awọn eniyan lati koju ijọba apapọ nipa jijoko si ile wọn titi ti Ajọ DSS yoo fi mu Nnamdi Kanu wa si ileẹjọ fun igbẹjọ rẹ ninu oṣu yii.''
''Mazi Nnamdi Kanu jẹ ajijagbara to n ja fun ẹtọ awọn eniyan paapaa ni orilẹede Naijiria , ti ko si fi igba kan hu iwa ibajẹ si ẹnikẹni.''
''O ṣeni laanu pe Ajọ DSS ti i mole lai gbe lọ si ileẹjọ lọna ati fi iya jẹ ni atimọle to wa naa.''
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Bí mo ṣe ná $88,521 lórí, igún, ìfun eerin, agbárí kìnnìhún láti gbé ẹbọ
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí?- Yomi Fabiyi
Osu Keje, ọdun 2021 ni ijọba Naijiria ati DSS fi panpẹ ọba mu Nnamdi Kanu lati oke okun wa si Naijiria, ti wọn si ti tii mole lati igba naa.
Ni Osu Keje, ni adajọ ni ileẹjọ giga ti ilu Abuja, Binta Nyako paṣẹ fun ijọba apapọ lati mu Kanu wa si ileẹjọ ninu Osu Kẹwaa yii, ki igbẹjọ rẹ le tẹsiwaju.

















