El-Adonai Evangelical Ministry: Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi

Oríṣun àwòrán, Others
O kere tan olujọsin mẹfa ni ina gbe ni ijọ El-Adonai Evangelical Ministry, ni agbegbe Abule Egba, nipinlẹ Eko.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni waya opo ina lo dede jabọ si ori orule ile ijọsin naa lasiko ti wọn n ṣe isin lọwọ ni owurọ Ọjọ Aiku.
Ohun to fa iṣẹlẹ naa ni pe ami idanimọ ile ijọsin naa kan opo ina to wa nibẹ, eleyii to fa ki ina gbe orule ijọ naa.
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?
- Bí mo ṣe ná $88,521 lórí, igún, ìfun eerin, agbárí kìnnìhún láti gbé ẹbọ
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí?- Yomi Fabiyi
Amọ ile ijọsin naa ko i tii fi orukọ awọn to lugbadi ijamba naa lede, ti wọn si ti wa ni ileewosan amọ ti wọn ko mọ ara nigba ti awọn oniroyin kan si awọn alaṣe lori iṣẹlẹ naa.
Awọn ti iroyin naa ṣẹlẹ loju wọn awọn mẹrin ku ninu awọn mẹfa ti iṣẹlẹ ina naa gbe. ti awọn meji to ku si wa ni ẹṣẹ kan aye, ẹṣẹ kan ọrun.
''A wa ninu ile nigba ti iṣẹlẹ naa waye ni nkan bi aago meje ni owurọ ọjọ isinmi.''
''A koko ro pe gaasi lo fa ina naa nitori ile ijọsin naa fẹ ṣẹ ayẹyẹ idupẹ ni aarọ ọjọ naa.''
''Nigba ti a jade lari pe asia ṣọọsi naa kan waya opo ina lo jẹ ina gbe awọn to wa ni abẹ rẹ. Ti awọn mẹrin ninu wọn si ku, ọdọlangba meji ati awọn ogo wẹẹrẹ meji.''

Oríṣun àwòrán, Others
''O ṣeeni laanu pe iṣẹlẹ yii fa rudurudu ni agbegbe naa ti pasitọ ijọ naa si salọ, ki awọn ọdọ adugbo naa to lọ jo ṣọọṣi naa ati gbogbo ohun to wa nibẹ.''
''Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to wa nibẹ lo jẹ ko rọlẹ, ti awọn eniyan si pejọ lati salaye bi nkan ṣe ṣẹlẹ ni agbegbe naa.''
Ọkan lara awọn ti ọfọ naa ṣe ni ọmọ ka ni oun mọ, oun ko ba ti jẹ ki ọmọ naa tete lọ si ileejọsin ni ọjọ naa nitori nigba to ji lo sọ wi pe oun fẹ lọ tun ṣọọṣi ṣe.
- Ìdí tí ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn fi ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn lórí ẹ̀tọ́ láti ṣẹ́yún
- Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Bolanle afurasí adigunjalè làyájọ́ òmìnira Nàìjíríà
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- Ẹ wo àwọn adarí ìjọ ní Naijiria tó tako abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 àti àwọn tó faramọ
- Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà
- Ohun márùn ún tí ejò ń jẹ
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
Iroyin ni ileeṣẹ panapana Lagos Fire Service ni wọn pe lati tete doola ẹmi awọn eniyan ki o to gbina to si le gbemi awọn eniyan tabi ba dukia jẹ.
''A ti fi to ileeṣẹ to n pin ina ka nipinlẹ Eko, Ikeja Electric Distribution Company ti wọn si ti pa gbogbo ina ni agbegbe naa, eleyii ti yoo doola ẹmi awọn eniyan ni agbegbe naa.''.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa bi o tilẹ jẹpe ohun ti awọn ri fihan pe kii ṣe pe awọn eniyan mọọmọ jẹ ki ina gbe awọn eniyan.
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà
- Ẹ wo àwọn adarí ìjọ ní Naijiria tó tako abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 àti àwọn tó faramọ
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?















