Ojú Bolanle rèé, afurasí adigunjalè tí òun àti àwon akẹgbẹ́ rẹ n kò ìbẹrù bá ará àdúgbò

Ọjọ ayajọ ominira Naijiria ni ọjọ Kinni, oṣu Kẹwaa jẹ fun ọpọ eeyan.
Ṣugbọn ọjọ yi ni afurasi adigunjale kan ati awọn akẹgbẹ rẹ yan laayo la ti lọ fi ko ibẹrubojo ba awọn ẹlẹran ara bi ti wọn.
Bi Oluwa ti ṣe fẹ, ọwọ palaba awọn afurasi yi segi nigba ti awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ribi mu wọn ki wọn to ribi digunjale ni Ilese Ijebu.
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí- Yomi Fabiyi
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Òní ní BBNaija 2021 ń parí, tani yóò fí 90m naira sara rindin?
Gẹgẹ bi atẹjade ti alukoro ọlọpaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi fi sọwọ si BBC, o ni nkan bi ago mejila abọ oru lawọn adigunjale yabo Silva Estate Odomalasa.
Lẹyin tawọn kan kepe ọlọpaa o ni awọn agbofinro agọ ọlọpaa Ilese Ijebu tara l sibẹ ti wọn si ribi koju awọn afurasi wn yi.
Awọn afurasi adigunjale naa sa wọ igbo nigba ti wn gburo ọlọpaa ṣugbọn ọwọ tẹ kan ninu wọn ti orukọ rẹ n jẹ Bolanle.
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Sina Jesu ní orúkọ́ mi báyìí, ń kò jẹ́ Shina Rambo mọ́ - Adigunjalè tẹ́lẹ̀ kìlọ̀
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá tí ìjọba dá sẹ̀ríà fún
- Ẹ wo àwọn adarí ìjọ ní Naijiria tó tako abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 àti àwọn tó faramọ
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
Ọpẹlọpẹ awọn araadugbo ti wọn jijọ le wọn, afurasi yi ko ba ri bi sa bi awọn iyoku rẹ.
Wọn ri ibọn agbelẹrọ kan lọwọ rẹ ati ọta ibọn.
Alukoro ọlọpaa Oyeyemi sọ pe wọn ti n tọ pinpin awọn to ku lọ ni ibamu pẹlu aṣẹ adele Kọmisọnna DCP Abiodun Alamutu.
Bẹẹ lo ni wọn ti gbe Bolanle ti ọwọ tẹ lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii kikun.















