Yomi Fabiyi tutọ́ sókè fojú gbàá lórí ọ̀rọ̀ onimọ̀ àyẹ̀wò Forensic tí Adájọ́ pé wá jẹ́rìí nìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha

yomi fabiyi

Oríṣun àwòrán, Instagram/yomi fabiyi

Yomi Fabiyi tun ti n sọko ọrọ pẹlu awọn eeyan lori igbẹjọ James Omiyinka Olanrewaju ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijesha.

Eyi ti a tun ri gbọ bayi ni i ṣe pẹlu ọrọ to kọ si oju opo rẹ ni Instagram to ti ni oun ko mọ idi tawọn eeyan fi n bu oun lori ijẹri onimọ ayẹwo.

Onimọ ayẹwo yi ni awọn oloyinbo n pe ni ''Forensic expert Witness.''

Ṣaaju ni ileẹjọ sọ pe ki ẹni yi wa sọrọ lori ifọrọwanilẹnuwo to ṣe fun ọmọdebinrin ti wọn ni Baba Ijesha ṣe aṣemaṣe pẹlu.

Ninu ọrọ to sọ loju opo Instagram, Fabiyi ni ki awọn eeyan sinmi eebu ati epe ti wọn n ṣẹ fun oun ki wọn si jẹ ki ileẹjọ ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ.

O ni: ''Ko si nkankan ti onimọ yi sọ ti a ko tii gbọ tẹlẹ.

Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ki ile ẹjọ ṣe iṣẹ wọn''

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Fabiyi ni: ''Wọn pe arabinrin yi wa lati wa sọrọ gẹgẹ bi olujẹri ni.

Ẹ gbọ nkan to sọ nile ẹjọ. Ko sọ pe oun ṣe ayẹwo ọwọ, iwadii dokita tabi nkan mii''

Aworan ọrọ Fabiyi loju opo Instagram

Oríṣun àwòrán, Instagram@yomifabiyi

Fabiyi ṣalaye pe nkan ti arabinrin naa kan ṣe ni pe ''o ba ẹni ti ọrọ kan ni ifọrọwerọ nikan ni.''

O rọ awọn to n bẹnu atẹ lu u pe ki wọn wa imọ si nipa eto igbẹjọ nitori ile ẹjọ ko tiẹ ti sọ pe ki wọn beere ọrọ lẹnu onimọ ayẹwo yi.

O ni ki awọn eeyan ṣe suuru lati gbọ idajọ ileẹjọ ki wọn to bẹrẹ si ni gbe lẹyin ẹnikankan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: