Baba Ijesha case: Amofin Ogala ṣàlàyé bó ṣe di agbẹjọ́rò fún Baba Ijesha

Amofin agba Babatunde Ogala SAN ati Ọlanrewaju James Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, other

Agba amofin to n duro fun gbajumọ oṣere tiata, Ọlanrewaju James Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, Amofin agba Babatunde Ogala SAN, ti sọ idi to fi n gbẹjọ ro fun Baba Ijesha.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu iwe iroyin The Punch, Amofin Babatunde Ogala ṣalaye pe ko si ohun kan to jẹ koriya fun oun lati duro fun Baba Ijesha ju wi pe wọn fi ẹjọ rẹ lọ oun oun si tẹwọgba.

Amọfin agba naa ṣalaye siwaju sii pe niwaju ofin ko si ipo, bakan naa lọrọ si jẹ niwaju oun pẹlu.

O ni ofin nikan loun mọ, nigba ti wọn gbe ẹjọ naa tọ oun wa, oun woo daradara ti oun si rii pe awọn ọna kan wa ti a fi lee ti ipasẹ ẹjọ naa mu ilanilọyẹ jade lori ofin.

Àkọlé fídíò, yyyy

Ni oṣu kẹrin ọdun 2021 ni iroyin jade pe Baba Ijẹsha lọwọ ninu aṣemaṣe kan pẹlu ọmọdebinrin kan.

Lẹyin asiko diẹ ni ahamọ ọlọpaa ni wọn gbe lọ si ileẹjọ to si n jẹjọ bayii niwaju Onidajọ Oluwatoyin Taiwo nile ẹjọ giga kan ni ilu Eko.

Wọn si ti sun igbẹjọ rẹ si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun 2021.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: