Myrtle Corbin: Obìnrin tó ló àìdàpé ara rẹ̀, sọ ara rẹ̀ di olówó

Josephine Myrtle Cobin

Oríṣun àwòrán, Wikipedia

Yoruba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ si ni tibi tire la dale aye, tibi tire la se ẹda eeyan, bi ire se wa ninu ibi, naa ni ibi wa ninu ire.

Bi ọrọ igbe aye arabinrin kan se ri ree, ẹni ti o ni aidape ara amọ ti ọba oke se e ni ogo pẹlu aidape ara naa.

Eyi si lo fidi rẹ mulẹ pe agbara wa ninu aidape ara, ta ba si lero pe Oluwa n se ibi, ase rere lo n se.

Arabinrin naa, Josephine Myrtle Corbin, lo ni ẹsẹ mẹrin, ile ọmọ meji, oju ara meji amọ ti ọba oke tun fun ni agbara lati bi ọmọ mẹjọ nile aye.

Gẹgẹ ba se ka loju opo Wikipedia, asise atọrunwa waye lasiko ti wọn loyun arabinrin naa, eyi to fa aidape ara fun.

Bi igbe aye rẹ si se lọ ree eyi to yẹ ka fi se arikọgbọn.

Àkọlé fídíò, Plastic to Petrol: Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ọ̀rá àti ike tí ò ń sọ dànù le mú owó gọbọi wálé fún ọ?

Igba iloyun ati ibẹrẹ aye Myrtle Corbin:

Orukọ baba Myrtle Cobin ni William H. Corbin, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn nigba to fun aya rẹ, Nancy Corbin, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn loyun.

Agbegbe Lincoln County, nilu Tennessee lorilẹede Amẹrika ni awọn obi Myrtle Corbin n gbe lakoko ti wọn loyun rẹ.

Lọjọ ti ọmọ tuntun naa de ile aye ni ọjọ Karun, osu Kejila ọdun 1868, ni wọn ri pe ibeji lo fẹ wa saye amọ ti ikeji rẹ ko lagbara lati di odidi eeyan, to si jẹ aabọ ẹda to so mọ ekeji rẹ lara.

Ẹsẹ mejeeji to yẹ ko jẹ ti ekeji rẹ ti ko pe odidi ẹda, ni Myrtle Corbin papọ, ti ẹsẹ rẹ fi di mẹrin, to fi mọ ile ọmọ ati oju ara ekeji rẹ lo dapọ mọ tiẹ, to fi di meji-meji fun.

Nigba ti wọn bi Myrtle Corbin pẹlu abuku ara yii, ẹnu ya awọn dokita, ti wọn si ri pe o dabu sinu iya rẹ ni, amọ wọn yi ipo to wa pada, to fi rọrun lati bii, bibẹẹ kọ ọrun ni aala fun tiya-tọmọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti wọn bi ọmọ yii, ko tii si isẹ abẹ rara lasiko naa lati gba ẹbi alaboyun tabi fi ya ibeji to lẹpọ.

Idi ree ti isẹda Myrtle Corbin fi se ara ọtọ lasiko ti wọn bi, ti ko si si ireti fun lati gbe ile aye.

Amọ riro ni ti eniyan, sise ni ti Ọlọrun, ọmọ naa n dagba, eegun rẹ si n le bii ti ọmọ to dape, bẹẹ lo n dagba ni ẹmi ati ni ọpọlọ.

Àkọlé fídíò, Brt-Train Accident: Grandma Oreoluwa ní ìlá alásepọ̀ ló ní òun máà se fún òun tó bá dé

Bawo lo se rọrun fun Myrtle Corbin lati gbe ile aye?

Awọn dokita si ri pe lati ibi ibadi ni ẹsẹ ikeji Myrtle Corbin ti so pọ mọ tiẹ, to si ni ara meji lati ibadi wa si isalẹ, eyi to mu ko tun ni oju ara ati ile ọmọ meji pẹlu.

Amọ o rọrun fun obinrin naa lati se akoso ẹsẹ ekeji rẹ naa, nitori ko gun to awọn ẹsẹ tiẹ mejeejiy, eyi to mu ko ma subu lasiko to ba n fi n rin.

Idi ni pe awọn ẹsẹ mejeeji ekeji rẹ naa lo wa ni aarin, ti wọn ko si ni agbara ra tabi ni imi ninu, ti ko si se fi rin rara.

Bakan naa, ọmọ ika ẹsẹ mẹta pere lo wa lara ẹsẹ ekeji rẹ naa.

Àkọlé fídíò, Adedapo Tejuosho: Olóyè tó bá dán ìdánkúùdán wò lára òkú mi yóò gba Ọlọ́run lọ́gàá

Awọn ara ti Myrtle Corbin fi abuku ara rẹ da, to sọ di olowo:

Arẹwa pọnbele ni Myrtle Corbin, ti ọba oke si fi ẹwa jinki rẹ lai naani abuku ara yii.

Koda, obinrin giga ni, iwọn giga rẹ si jẹ ẹsẹ bata marun, o mọ lawọ, o ni ọpọlọpọ irun lori, to si tun ni oju buluu.

Nigba to di ẹni ọdun mẹtala, okiki obinrin naa ti kan yika agbaye nipa ọna to n gba mura, eyi to ya ni lẹnu pupọ.

Baba obinrin yii lo kọkọ ronu nipa ọna ti yoo fi wulo, to si bẹrẹ si patẹ rẹ ni awọn gbọngan sinima, ti ọpọ eeyan si n ya wa fi owo ribiribi wo akanda ẹda obinrin ẹlẹsẹ mẹrin naa.

Se ni Myrtle Corbin si n lo abuku ara rẹ lati fi pa owo nipa imura rẹ. Yoo si wọ awọn ọmọ ika ẹsẹ rẹ ti ko dape naa ni asọ ti oyinbo n pe ni socks.

Bakan naa ni yoo wọ bata fun awọn ẹsẹ ekeji rẹ to wa ni aarin ẹsẹ tiẹ, bi o tilẹ jẹ pe kii fi awọn ẹsẹ naa rin.

Nigba to ya, awọn eeyan to jẹ gbajumọ ninu isẹ amuludun bii P.T Barnum, Ringling bros ati Coney Island n ba Myrtle dowo pọ, ti wọn si n gbe isẹ afihan ara rẹ to n se larugẹ.

Okiki Myrtle Corbin si tan debi pe o n pa owo to to ọtalenirinwo o din mẹwa dọla ($450) ni ọsẹ kan, eyi to jẹ owo nla nigba naa.

Àkọlé fídíò, Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà

Igbeyawo Myrtle Cobin:

Nigba to pe ẹni ọdun mọkandinlogun, Myrtle Corbin se igbeyawo pẹlu James Clinton Bicknell, ẹni to pọn ni dandan fun aya rẹ lati mase patẹ aidape ara rẹ fun aye mọ.

Awọn mejeeji bẹrẹ isẹ oko dida ti ọkọ rẹ n se tẹlẹ, eyi to fihan pe ifẹ tootọ ni James ni si Myrtle, kii si se tori owo ti obinrin naa ni, lo se fẹ.

Amọ lẹyin igbeyawo wọn ni ọkọ rẹ ri pe oju ara meji ni Myrtle ni, ti oju ara keji si jẹ ti ibeji rẹ, eyi to mu ki obinrin naa jẹ obinrin kan soso lagbaye ti yoo ni oju ara meji.

Bakan naa, nigba to loyun ni asiri tu sọwọ awọn dokita pe ile ọmọ meji naa tun ni obinrin aramọnda yii ni, to si fi ile ọmọ apa osi loyun.

Lẹyin o rẹyin, ọmọ mẹjọ ni Myrtle Cobin bi sile aye amọ mẹta pere lo gbẹyin rẹ.

Àkọlé fídíò, 2023 Nigeria Election: Ìgbàgbọ́ wa ní pé Nàìjíríà ṣì máa dùn lẹ́yìn ìdìbò ọ̀la yìí

Aisan ati iku Myrtle Cobin:

Nigba to di ọdun 1928, ti Myrtle Corbin pe ẹni ọgọta ọdun ni aisan ara kan kọlu u, eyi to ba awọ rẹ jẹ, ti ko si gbọ wiwo.

Lasiko yii, ko tii si iwosan fun arun ara naa ti wọn n pe ni Erysipelas, a streptococcal skin infection, amọ lode toni, horo oogun diẹ ti to lati wo aisan naa.

Nigba to di ọjọ Kẹfa, osu Karun ọdun 1928, Josephine Myrtle Corbin-Bicknell jade laye nilu Cleburne nipinlẹ Texas, eyi to fi opin si igbe aye obinrin kan soso to ni ẹsẹ mẹrin.

Se ni awọn mọlẹbi rẹ si n sọ oku ati posi rẹ lọwọ-lẹsẹ, ki awọn adigunjale maa baa ji gbe salọ.

Koda, awọn onisẹ iwadii, afi nnkan isẹmbaye pamọ atawọn onisegun oyinbo gan gbe owo kalẹ lati gba oku rẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ taku, ti wọn si tubọ n sọ oku rẹ.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Ẹkọ ti itan igbe aye Josephine Myrtle Corbin kọ wa:

Ẹkọ akọkọ ti itan aye Myrtle Corbin kọ wa ni pe ka ma jẹ ki aidape tabi abuku ara di wa lọwọ lati mase gbe ohun rere se nile aye.

Ẹkọ keji ni pe igbe aye Myrtle Corbin kọ wa lati mase jẹ ki ipo ta n la kọja se akoso aye wa nitori igba ko tọ lọ bii orere, aye ko tọ lọ bi ọpa ibọn.

Myrtle Corbin jẹ alabuku ara amọ eyi ko ni ko ma de ibi giga nile aye , o ni ẹkunrẹrẹ ayọ ati ohun amuyangan, eyi to yẹ ki awa naa fi se awokọse rere.

Lakotan, igbe aye Myrtle Corbin kọ wa lati ni ifarada, ipamọra ati ifiraẹnijin ni ipokupo ti a ba wa nitori ohun gbogbo lo n sisẹ pọ fun rere.