Zoom Wedding: Àwọn ọkọ àti ìyàwò ló ní àwọn kò leè sún ọjọ́ ayọ̀ wọn síwájú.
Orin o tiṣe fun mi, oti ṣe fun mi, oun baba, iya ko le ṣe, o ti ṣe fun mi lo gbẹnu ọkọ iyawo ori Zoom.
Pasitọ sọ ojuṣe tirẹ gẹgẹ bii ilana ofin Naijiria. "O ṣe pataki fun mi lati ri i daju pe awọn lọkọlaya yii ti ṣe igbeyawo labẹ ofin naa ki a to le ṣe ti ilana Kristẹni lori ayelujara Zoom".
Pasitọ ṣalaye pe lai si eyi, gbogbo igbiyanju lati jẹ ki igbeyawo naa ba ofin mu ko lee jẹ itẹwọgba tori awọn ofin to rọ mọ eyi lorilẹede Naijiria.
Ṣaaju, iyawo funrarẹ ti sọ idi ti igbeyawo yii ṣe waye lasiko yii pe 'Coronavirus ló mú mi fẹ́ ọkọ mi tí a sì ṣèyàwó lóríi ‘Zoom’


Ile iṣẹ BBC ba Pasitọ to so ọkọ ati iyawo pọ sọrọ to jẹ Pasitọ ijọ HICC.
O ni awọn ni lati wa ọna ara ọtọ lati ṣe iṣẹ iranṣẹ wọn paapaa fun awọn to ba nilo rẹ lọna ara ọtọ. Lara iṣẹ iranṣẹ naa si ni wipe bi awọn eeyan ba fẹ gbeyawo.
"A fun awọn to ti baba da ọjọ sọna si asiko yii lanfani lati yan eyi ti wọ́n ba fẹ. Yala ki wọ́n sun ọjọ igbeyawo wọn siwaju ṣugbọn ọpọ ni inu wọn ko dun lati sun ọjọ ayọ wọn siwaju".

Bakan naa, awọn abani ṣeto ayẹyẹ naa ba BBC sọrọ nipa bo ṣe maa n ri bi iru iṣẹlẹ yii ba ṣẹlẹ.
Koda, ọkọ ati iyawo rẹ Ademola ati Yinka ko ri gbogbo ọrọ odi ti ẹnikẹni le maa ro o, wọn sọ bi idunu wọn ko ṣe ṣee fẹnu sọ rara.