Covid-19 Wedding: Ọkọ àti Ìyàwó yìí ti dájọ́ sọ́ná ṣáájú Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Courtesy of the couple
"Maa fẹ lati maa ranti ọjọ oni tii ṣe ọjọ ayẹyẹ wa titi di ogun ọdun si isinsinyii... Kii ṣe tori asiko ajakalẹ arun yii nikan ṣugbọn tori mo ti yan lati gbe iyoku aye mi pẹlu Reme."
Ayokunle Sulaiman ati aya rẹ, Reme Olotun ti n ka ọjọ ka oṣu si ọjọ ayẹyẹ wọn eyi to yẹ ko waye ni ile itura Sheraton ni ipinlẹ Eko, orilẹede Naijiria, lọjọ ti wọn da, ọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin ọdun 2020.
Ṣugbọn bi ọrọ ajakalẹ arun to wa lode ṣe da ni lagara ti dédé sọ Reme ẹni to n ṣiṣẹ ni ilu Canada si okunkun alẹ pẹlu bi ko ṣe ni lanfani lati rinrinajo lọ si orilẹede Naijiria lati lọ fẹ aayo ọkan rẹ, Ayokunle.
O ba mi lojiji" Reme sọ fun BBC. "Mo ti lọ ra gele igbeyawo mi, bata ati gbogbo nkan mii ti mo nilo fun iyawo".
Ni tirẹ, iṣe ti wọn fi n sun ọjọ isede ati irina siwaju ni gbogbo igba ti wa di ohun ti Ayokele ko lee gbagbọ mọ. Lọgan lo ba bẹrẹ si nii ronu ọna mii ti wọn lee gba ṣe inawo wọn.
Ọkọ ati aya ba pada pinu lati ṣegbeyawo wọn lọjọ kan naa ti wọn da iyẹn ọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin ti pasitọ si dari isin igbeyawo naa lori aapu ayelujara kan to n jẹ 'Zoom'.
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú
- Ìjọba Nàìjíríà ti parí ìwádìí lórí àgbo Covid-Organics ti Madagascar kó ránṣẹ́ sí i
- Wo àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí tó ń fi ẹ̀mí wọn wéwu kí Abuja leè mọ́ tónítóní
- Ọkùnrin kan pa ara rẹ̀ sínú ọgbà àjọ TRACE tó n mójútọ ìrìnnà ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ogun
"Ohun gbogbo da bii adapọ aidunu, ireti, ibinu koda to fi mọ igbagbọ pe ohun gbogbo ṣi maa dara", Reme sọ fun BBC."Gbogbo Igba lo maa n ni ọna abayọ si ọrọ to ba n ru ni loju", o sọ eyi fun ọkọ rẹ.
Ṣe ofin Naijiria faaye gba igbeyawo ori ayelujara?
Ko si ofin kankan to sọrọ nipa igbeyawo ori ayelujara lorilẹede Naijiria.
Ofin igbeyawo ni Naijiria fun awọn ololufẹ ni anfani meji - yala igbeyawo ni ile ẹjọ tabi ni ile ijọsin.
Ṣugbọn nitori isede, agbẹjọro kan, Abisola Ogunbadejọ sọ pe awọn to ṣe inawo yii ti bere ibeere fun iwadii boya aye gba wọn labẹ ofin fun ohun ti wọn ṣe tori naa wọn ni atilẹyin onimọ ofin ni Naijira.
Arabinrin Ogunbadejo wa sọ pe bi o ti wu ki igbyawo ori ayelujara tẹ ọpọlọpọ lọrun to, o ṣi ṣe pataki ki wọn lọ ṣegbeyawo ni ile ẹjọ nitori bi ọlọjọ ba de tabi atubọtan ohun ti wọn ṣe lọjọ iwaju.














