Service Chiefs: Ilé aṣòfin ní kí àwọn ọ̀gá àgbà ológun kúrò lẹ́nu iṣẹ́

Nigeria service chiefs

Oríṣun àwòrán, NTA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn aṣofin orilẹede Naijiria ti funpe si awọn ọga agba awọn ologun ni ileeṣẹ ologun, ologun ori omi, ọlọpaa, ologun oju ofurufu, aabo, ati ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹnu lati fi ipo wọn silẹ.

Awọn aṣofin ni bi awọn sọja ṣe n foju ri oriṣiriṣi mabo lọwọ awọn jaguda kun lara idi to fi yẹ ki wọn fiṣẹ silẹ.

Ọjọ iṣẹgun ọsẹ yii lawọn ile igbimọ aṣofin fẹnu ko lori ọrọ yii pe yala ki awọn ọga ọga lẹnuuṣẹ ogun yii kọwe fipo silẹ tabi ki wọn gba idaduro tori iṣoro aabo lorilẹed yii ti n pọ ju ko si fẹ lopin.

Ileeṣẹ aarẹ gan sọ pe awọn ri igbesẹ ti ile aṣofin gbe, wọn si sọ pe yiyan tabi dida ọga awọn ologun duro, ọwọ aarẹ lo ti n wa bẹẹ si ni pe aarẹ yoo ṣe oun to tọ bi asiko ba ti to.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Ohun to wa nidii ọrọ yii gangan ni pe awọn ologun wa n gbiyanju daadaa, kii ṣe kekere...

Sẹnetọ Ali Ndume lo sọ eyi, o ni "a ni lati maa fiṣẹ yin wọn ki a si maa pese fun wọn. Wọn n fi ẹmi wọn lelẹ fun gbogbo wa eyi si ba ni lọkan jẹ pe ọpọlọpọ wọn lo ti pa jijagun ti".

Eyi lo mu ki awọn aṣofin lọjọ kọkanlelogun oṣu keje ni ki awọn mii rọpo awọn ọga ologun to wa nibẹ lọwọlọwọ.

Ki lo mu ki eleyi ṣẹlẹ gan?

Laipẹ yii ni awọn ọmọ ofun Naijiria foju wina ọpọlọpọ nkan loju ogun to bẹẹ ti awọn kan ti n boju wẹyin loju ogun ti wọn si n fiṣẹ wọn silẹ.

Sẹnetọ Ahmed Lawan ni iye awọn ologun to ti fiṣẹ silẹ ti to igba bayii wọn si ni awọn yo tọpinpin bi iru nkan bayii ṣe ṣẹlẹ.

Awọn aṣofin sọ pe awọn jaguda ti bẹrẹ si nii dena de awọn ologun ninu igbo.

Bakan naa, iroyin ti n jade bi awọn ologun ṣe n sọrọ pe awọn nkan ijagun ko to awọn ja ogun nla nla bii eyi ti awọn ajijagbara n ko.

Ninu fọnran to gba ori ayelujara kan ni sọja kan ti n sọ pe o ti su awọn lati maa sin orilẹede wọn.

Asiko idakẹrọrọ

Awọn aṣofin ni awọn yoo ṣe asiko idakẹrọrọ iṣẹju kan fun awọn ologun awọn yoo si funpe si ijọba apapọ lati ṣe kia kia pese awọn nkan ijagun fawọn ologun.

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....