Buhari: Isa Funtua ti wọ káà ilẹ̀ sùn ní ìlú Abuja

Mamman Daura tare da Marigayi Isma'ila Isa Funtua

Oríṣun àwòrán, Twitter/@ibrahimado__

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Wọn ti ṣeto isinku amugbalẹgbẹ aarẹ Muhammadu Buhari, Isma'ila Isa Funtua ni mọṣalaṣi Shehu Shagari, to wa ni Area 1, Abuja.

Oloogbe ọhun si ti wọ kaa ilẹ sun ni iboji Gudu ni ilu naa.

Eto isinku ọhun ni wọn ṣe pẹlu ilana ijinasiraẹni ti ajọ NDCD gbe kalẹ nitori ajakalẹ arun Coronavirus to wa lode.

Awọn eeyan jankan jankan ni Naijiria lo peju sibi ẹyẹ ikẹyin oloogbe naa, bẹẹ lawọn oloṣelu ko gbẹyin pẹlu.

Aarẹ Buhari ni iku Funtua jẹ ibanujẹ nla fun oun, ati pe iroyin iku naa ba oun lojiji.

Jana'izar Isah Funtua

Bẹẹ naa ni igbakeji aarẹ ana, Atiku Abubakar sọ pe ọfọ nla ni iku Funtua jẹ, lẹyin naa lo ba awọn ẹbi rẹ kẹdun.

Atiku lo fi ẹdun ọkan rẹ lede loju opo Twitter rẹ nibi to ti gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Bakan naa ni aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, Bukola Saraki ba ẹbi oloogbe naa kẹdun lẹyin to dagbere faye.

Saraki sọ pe ẹni iyi ni Funtua, o si jẹ orisun ọgbọn fun awọn to n bọ lẹyin ko to faye silẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Gbajumọ oloṣelu ati agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-ṣofun tẹlẹ, Yakubu Dogara naa ba gbogbo ẹbi Funtua kẹdun iku rẹ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, Olofa ina: ẹ parí òwe yìí pé ìgbà tí ara bá tu ìgbẹ́ láà ri eṣú....

Buhari: Isa Funtua, Abba Kyari, àti Zulaihat Buhari jẹ́ àwọn tó súnmọ́ Aàrẹ tó papòdà láìpẹ́

Funtua/Zulaihat Hardo/Zulaihat Buhari/Kyari

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Isa Funtua/Zulaihat Hardo/Zulaihat Buhari/ Abba Kyari

Yatọ si ọkan lara awọn eeyan to sunmọ Aarẹ Muhammadu Buhari, Isamaila Isa Funtua, to ku lọjọ Aje, Aarẹ ti padanu awọn eeyan to ṣe pataki si i ni igba diẹ sẹyin.

Bẹẹ ko sẹni ti ko ni ku, adura BBC ni pe ki ọjọ jinna sira wọn fun koowa.

Diẹ lara wọn niyii:

Zulaihat Adamu Hardo

Aimọye igba ni Aarẹ Buhari ti sọrọ nipa iku iya rẹ to waye l'oṣu Kejila, ọdun 1988.

Buhari maa n sọ pe iku iya oun jẹ ọkan lara awọn iṣẹlẹ ibanujẹ to ti ṣẹlẹ si i laye, nitori pe iya rẹ nikan lo tọ ọ dagba, lẹyin ti baba rẹ ku nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrin.

Oṣu Kejila, ọdun 1988, ni iya to bi Aarẹ Buhari, Zulaihat Adamu Hardo, ku

Oríṣun àwòrán, RARIYA

Àkọlé àwòrán, Oṣu Kejila, ọdun 1988, ni iya to bi Aarẹ Buhari, Zulaihat Adamu Hardo, ku

Ẹya Fulani ni iya Aarẹ Buhari, Zulaihat, lati ilu Daura nipinlẹ Katsina.

Ko si fẹ ẹ si akọsilẹ nipa ọdun to di iyawo Aarẹ Buhrai, ṣugbọn awọn kan sọ pe ni nkan bi ọdun 1930 ni.

Zulaihat (Nee) Buhari

Oríṣun àwòrán, ZAINAB BUHARI FANS/FACEBOOK

Zulaihat (Nee) Buhari

Awọn iroyin kan sọ pe o pẹ ki Aarẹ Buhari to turaka lẹyin iku ọmọbinrin rẹ, Zulaihat lọdun 2012.

Zulaihat ni ọmọbinrin akọkọ ti aarẹ bi, aarẹ si fẹran rẹ pupọ, eyi to mu ki aarẹ fi orukọ iya rẹ sọ ọ.

Ọmọbinrin naa ku sileewosan aladani kan nilu Kaduna, lẹyin ọjọ meji to bimọ, nitori aisan aromọleegun 'Sickle cell Anaemia.

Mallam Adamu Hardo

Fun awọn ti ko mọ, ọkunrin yii lo bi Aarẹ Buhari.

Igba ti aarẹ wa l'ọmọ ọdun mẹẹrin ni baba naa ku, nilu Daura nipinlẹ Katsina.

Ẹya Fulani ni Mallam Adamu Hardo, o si tun jẹ oloye nilu Daura nigba aye rẹ.

Baba ọlọmọ, ati iyawo pupọ ni. Koda, Aarẹ Buhari ni ọmọ rẹ kẹtalelogun.

Aarẹ ma n sọ inira ti aini baba laye mu ba a nigba to wa ni èwe.

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, BASHIR AHMAD/TWITTER

Abba Kyari

Oṣu mẹta sẹyin ni aarun coronaviru pa olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Buhari tẹlẹ, Abba Kyari.

O jẹ ọkan lara awọn ọrẹ timọtimọ ti aarẹ ni.

Kyari si ni oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipo to ga, ti Covid-19 kọkọ pa ni Naijiria.

Aarẹ Buhari sọ lẹyin ti Kyari ku pe, ọpọlọpọ ọdun ni awọn ti jọ n ṣe ọrẹ, titi di akoko iku rẹ.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2015, lo kọkọ yan Kyari si ipo olori oṣiṣẹ, to si tun pada yan-an nigba to wọle saa keji.

Samaila Isa Funtua

Oríṣun àwòrán, FUNTUA PAGE/ FACEBOOK

Samaila Isa Funtua

Iku doro, iku mu amugbalẹgbẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lọ ni Abuja

Ọkan gboogi ninu iṣejọba Aarẹ Buhari, Malam Ismaila Isa Funtua ti jade laye ni ẹni ọdun mejidinlọgọrin.

Iroyin ni aisan ọkan lo fa iku ojiji to mu u lọ, lẹyin ti o lọ si ile iwosan fun ayẹwo ara rẹ.

Bawo ló ṣe ṣẹlẹ nigbà tí ọlọjọ wọle de wẹrẹ wa mu Isa Funtua lọ?

Ẹ wo bí Isa Funtua, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Aàrẹ Buhari ṣe lo ìgbé ayé rẹ

Isa Funtua: Ohun mẹ́jọ tí ẹ kò mọ̀ nípa Isa Funtua, ana Aàrẹ Buhari tó dolóògbé

Àwọn ǹkan pataki ti oloogbe Isa Funtai ṣe lókè eèpẹ̀ kó to dagbere faye pe o digboṣe.

Ọrẹ atigba ewe ni Aarẹ Buhari ati Isa Funtua jẹ, wọn si jọ maa n jẹun ninu awo kan naa.

Oríṣun àwòrán, @BASHIRAHMAAD

Àkọlé àwòrán, Ọrẹ atigba ewe ni Aarẹ Buhari ati Isa Funtua jẹ, wọn si jọ maa n jẹun ninu awo kan naa.

Bi ara ẹni ba ti n powe fun eeyan ni onikaluku a ti mọ pe oun nilo itọju lasiko.

Aisan ọkan ti n ba oloogbe Isa Funtua finra tẹlẹ ni eyi to ti n gab itọju loorekoore nipa rẹ tẹlẹ.

Iroyin ni ki o to lo si ileewosan ni eyi to mu ti ọlọjọ dani yii ni Isa ti sọ fun awọn ẹbi rẹ wi pe oun n lọ ṣe ayẹwo ara oun, ti oun yoo si gba ibẹ lọ gẹ irun ori oun.

Oni, Ọjọ Iṣẹgun ni wọn yoo sin oku rẹ ni ilana ẹsin Musulumi.

Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Ohun ti a mọ nipa Isa Funtua, ọrẹ Buhari to dagbere fun aye re:

Ismaila Isa Funtua ni wọn bi ni ilu Funtua ni Oṣu Kini, ọdun 1942, ti o si ti kekere gba ẹkọ imọ Quran.

Lẹyin naa lo lọ si ile iwe girama ni Zaria.

Bakna naa ni Isa jẹ ọkan lara awọn to kọkọ lọ si ileewe ẹkọṣẹ ijọba ti Federal Training Centre, Kaduna ati ile iwe giga ti Zaria.

Buhari ati Isa

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Bi eeyan ba ri ọlọrọ rẹ ......

Isa Funtua lọ si ile iwe giga ti Manchester to wa ni Ilẹ Gẹẹsi

Funtua di ana Aarẹ Buhari nigba ti ọmọ rẹ, Abubakar fẹ ọmọ Aarẹ Buhari, Safine (lami).

Malam Isa ni oludasilẹ Iwe Iroyin Democrat Newspaper, ti o si tun jẹ Aarẹ tẹlẹri fun ẹgbẹ Newspaper Proprietors Association of Nigeria (NPAN).

Àkọlé fídíò, Lockdown updates: Naira Marley gbóríyìn fún Jude Chukwuka pẹ̀lú #1 míliọnù

Funtua jẹ ojulowo oniṣowo ni igba aye rẹ, ti o si ṣiṣẹ ijọba fun ọgbọn ọdun

O ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ni ileeṣẹ ijọba ti National Institute of Policy and Strategic Studies (NIPSS), Kuru.

Bakan naa lọ ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ni ẹka eto (Administrative Officer) ni ileeṣẹ Katsina Native Authority fun ọdun meje.