Madagascar Covid 19 Update: Àgbo Covid-19 Madagascar kò ṣiṣẹ́, àwọn ènìyàn tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kú níbẹ̀

Agbo Covid-Organic

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ orílẹ̀èdè Madagascar, fi ọwọ́ sọ̀yà lórí àgbo nàá, kódà, ó mu lára rẹ̀ lójú gbogbo ayé lórí tẹlifísàn

Ileewosan lorilẹ-ede Madagascar ti n tiraka lati tọju awọn alarun Coronavirus nitori arun naa ti peleke si nibẹ.

Bi o tile jẹ pe Aarẹ orilẹ-ede Madagascar, Andry Rajoelina n lọgun pe agbo awọn n koju arun Coronavirus, Ajo Eto Ilera Lagbaye (WHO) ti ṣekilọ lori lilo agbo naa nitori ko gba ontẹ ayẹwo finifini.

Laarin oṣu kan, iwadii fihan pe iye awọn to ti lugbadi arun naa ti peleke si ni lorilẹ-ede naa.

Eniyan ẹgbẹrun lọna mẹtala lo ti lugbadi arun naa, ti eniyan mejilelọgọjọ si ti ku.

Amọ bi iye eniyan ṣe n peleke si to ni arun Coronavirus naa ni Aarẹ Andry Rajoelina n sọ wi pe agbo Madagascar yii ni ọna abayọ si arun Coronavirus, ti o si ṣe ifilọlẹ rẹ ni Oṣu Kẹrin.

Àkọlé fídíò, Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America

Ileeṣẹ Madagascar Institute of Applied Research ni wọn lo egbogi artemisia, to n koju aisan iba ati awọn egbogi miran lati fi ṣe akojọpọ agbo naa.

Orilẹede naa ti polongo oogun ohun gẹgẹ bi oogun to n dena to si n ṣewosan fun arun naa, ti wọn si ti fun awọn akẹkọọ to wa nile iwe mu lati bi oṣu mẹrin ṣẹyin.

Saaju ninu oṣu yii, aarẹ naa ṣi n pin agbo naa kaakiri pẹlu awọn ohun iranwọ miran bii irẹsi, ororo, suga fun awọn eniyan to wa ni igberiko.

Amọ, Ajo Eleto Ilera Lagbaye, WHO ni awọn ṣe agbatẹru fun awọn oogun iwosan ibilẹ, amọ awọn gbọdọ ri ẹri ayẹwo imọ sayẹnsi wi pe awọn agbo yii le e ṣe awotan aarun Coronavirus.

Àkọlé fídíò, jkkkkk

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ìjọba Nàìjíríà ti parí ìwádìí lórí àgbo Covid-Organics ti Madagascar kó ránṣẹ́ sí i

Awọn alaṣẹ orilẹ-ede Naijiria ti sọ pe awọn ko ri ẹri tabi aridaju pe àgbo ti orilẹ-ede Madagascar ṣe fun iwosan coronavirus n ṣiṣẹ.

Ajọ to wa fun iwadii ijinlẹ ati idagbasoke nipa oogun ni Naijiria, National Institute of Pharmaceutical Research and Development (NIPRD) lo fi ikede naa sita lẹyin iwadii to ṣe lori agbo naa.

Ṣugbọn awọn alaṣẹ ajọ NIPRD tun sọ pe iwadii ko pin si ibi kan.

Agbo Covid-Organic

Oríṣun àwòrán, AFP

Oṣu Karun ni orilẹ-ede Madagascar fi agbo na, Covid-Organics ranṣẹ si Naijiria, ati awọn orilẹ-ede ilẹ Africa kan, ṣugbọn Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe oun ko ni fi ọwọ si lilo agbo naa ni Naijiria titi di igba ti awọn alaṣẹ eto ilera ba buwọlu u.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹ lu ijọba nigba naa pe wọn ko fẹ ẹ ṣe atilẹyin fun akẹgbẹ rẹ nilẹ Africa ni.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ àgbo lè ṣe òògùn coronavirus?

Bakan naa ni ajọ eto ilera l'agbaye, WHO, sọ pe ko si ẹri pe oogun kankan ti wa fun iwosan Covid-19, lẹyin ti

Agbo Covid-Organic

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ orílẹ̀èdè Madagascar, fi ọwọ́ sọ̀yà lórí àgbo nàá, kódà, ó mu lára rẹ̀ lójú gbogbo ayé lórí tẹlifísàn

Ewe Artemisia ni eroja gboogi ti wọn fi ṣe agbo naa, ati awọn ewe miran to wa l'orilẹ-ede Madagascar.

Olori ajọ NIPRD, Dokita Obi Adigwe, sọ fun BBC pe "iwadii ti a ṣe fihan pe agbo naa ni agbara lati mu ki eeyan hu ikọ jade, to si tun din iba ku lara awọn ẹranko ti wọn ti dan-an wo.

Ṣugbọn o ni NIPRD ti gba ijọba Naijiria nimọran pr ko si ẹri pe àgbo naa le dena tabi wo Covid-19 san.

"Ti a ba ni akoko ati awọn nkan to yẹ, o ṣeeṣe ki a ṣi ri arigbamu."

O ti le ni ẹgbẹrun mẹtaledinlogoji eeyan ti Covid-19 ti ran ni Naijiria, awọn to le ni ẹgbẹrin si ti ku.

Àkọlé fídíò, Ṣẹ́ lóòtọ́ ní ginger àti garlic lè pa àrun Coronavirus?