Coronavirus: Irọ́ ńlá ni pé ewé dongoyaro lè wo aàrùn coronavirus

Àkọlé fídíò, Irọ́ ńlá ni pé ewé dongoyaro le wo ààrùn coronovirus

Lẹyin ti arun Coronavirus di tọrọ fọnkale lọpọ orilẹede kaakiri agbaye, ọpọ awọn eeyan lo n sọ lori ayelujara pe ewe dongoyaro le wo aarun coronavirus.

Ko si ohun to jọ bẹẹ rara! Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ to n risi eto ilera lagbaye, WHO ṣe sọ, ewe dongoyaro ko le wo aarun covid-19.

Ajọ WHO ṣalaye pe ko tii si oogun tabi abẹrẹ to le wo aarun coronavirus lọwọlọwọ bayii.

Ajọ naa ni ewe dongoyaro ko tiẹ le ṣe adinku aarun naa lara alaisan.

Bi ọrọ ṣe jẹ wa ninu fidio yii.