Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America

Àkọlé fídíò, Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America

Mo ti ṣiṣẹ olutọju arugbo ri ni America- Victor Agunbiade.

Victor Agunbiade ọmọ Baba Ijẹbu ni ipinlẹ Ogun to jẹ Guusu Naijiria to n gbe ogo ilẹ Oodua ga lọwọlọwọ ni idi iṣẹ ọmọ ogun oju omi ni America ni BBC Yoruba gbe wa fun un yin nipa akọni Yoruba lọtẹ yii.

O sọrọ ni kikun bo ṣe bẹrẹ irinajo rẹ ni ilẹ ajeji ni America ki ori to fi ọna iṣẹ aṣeyọri han an.

Victor Agunbiade

Victor Agunbiade gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran lati fi ootọ inu ṣiṣe aje wọn nibiklibi ti ori ba da wọn si

Victor Agunbiade

Bakan naa lo mẹnuba ipa ti igbagbọ ninu Olorun n ko ninu igbiyanju ẹda laye pẹlu imọran pe ki awọn ọdọ maa beere lọwọ ori ki wọn to gbe igbesẹ nitori oju ala ni oun ti ri ara oun nidi iṣẹ to sọ oun di olokiki yii lẹyin adura.

Victor Agunbiade

Victor Agunbiade tun mẹnuba bo ṣe ṣiṣẹ agbalẹ, ẹni to n fọ abọ ati ni 'factory' ki oun le tọju iya agba ati ẹbi to fi silẹ ni Naijiria ki o to lọ kawe sii to si di ọga agba yii

Victor Agunbiade
Victor Agunbiade

Ohun rere ti Victor Agunbiade n ṣe nilẹ okeere yii jẹ iwuri fun iran Yoruba ati Naijiria lapapọ paapaa lasiko yii ti awọn bii Hushpuppi ati awọn miran n ba orukọ Naijiria jẹ.