Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Kini Oluwa ko le ṣe?

Ibeere nla ti idahun rẹ jẹ pe Ko si ohun ti Olorun ko le ṣe ni ifọrọwerọ BBC oni gbe dani loju ọpọn wa.

Tọkọtaya ti O wu Olorun lati pa lẹrin ayọ lasiko yii

Ifeoma Thelma ati Onyemaechi ni wọn ṣe igbeyawo lọdun 2014 ti wọn si bẹrẹ si ni woju Oluwa fun ẹbun ọmọ rere to jẹ ìní Oluwa.

Lọdun 2019 ni wọn di iya ati baba Ibẹfa lẹyin gbogbo igbiyanju wọn lori ati di ọlọmọ laye.

Ọmọ ọkunrin mẹrin ati ọmọbinrin meji lanti-lanti ni Oba Oke fi jinki tọkọtaya Chiaka lẹẹkanṣoṣo nigba ti o ṣamin si IVF ti wọn ṣe to si yọ wọn kuro lagan nigba to wu u.

Awọn ẹbun ọmọ mẹfa naa

Ifeoma ṣalaye fun BBC pe niṣe ni ẹnu ya gbogbo eeyan nile iwosan ni America ti oun lọ bimọ si nigba ti wọn kọkọ gbe ọmọ mẹrin ti fọto 'Scan' sọ pe o wa nibẹ tẹlẹ sita, ti wọn tun ri mii sii.

Okunrin mẹrin ati Obinrin meji lantilanti
Iya ikoko ninu oyun ibẹfa

Thelma ni awọn mọ pe Olorun to fun awọn ni awọn ọmọ mẹfa yii lẹẹkan ṣoso naa ni yoo pese owo ti awọn yoo fi tọ wọn bi o ṣe yẹ!

Ikoko mẹfa

BBC gbadura fun gbogbo ololufẹ wa to n woju Oluwa pe, iru ẹbun wọnyii a wọle tọ yin bi o ṣe wu yin laipẹ.

Awọn ikoko mẹfa naa
ẹbun ọmọ mẹfa