Lebanon returnees: Àwọn aláànú àti ìjọba Lebanon ló san owó tí a fi ń kò àwọn ọmọ Nàìjíríà tó há sí Lebanon padà- Dabiri

Àkọlé fídíò, jkkkkk

Abike Dabiri: Ajo ko dabi ile, ẹ jẹ ki gbogbo wa tun Naijiria ṣe.

Abike Dabiri to jẹ olubadamọran pataki fun Aarẹ Buhari lori ọrọ ilẹ okeere ṣalaye fun BBC ibi ti iṣẹ de duro lori kiko awọn ọmọ Naijiria to ha si Oman ati Lebanon wa sile lasiko ajakalẹ arun coronavirus yii ati iṣẹlẹ ibugbamu to waye ni Lebanon.

Awọn ti Naijiria ko de tẹlẹ ti fi ayọ wọn han si Oluwa ati Naijiria.

Dabiri ki Makinde, Sanwo Olu ati Oyetola ku iṣẹ iranlọwọ ti wọn n ṣe lati ri awọn ọdọ yii ko wa sile pada.

O kilọ pe ki gbogbo ẹbi maa kilọ fun awọn ọmọ wọn ki wọn yẹra fun ẹtan pe orilẹ ede miran dara ju Naijiria lọ.

O ni Lebanon ti ni ko si fisa mọ fun awọn ọmọ Naijiria lati wa ṣe ọmọ ọdọ nibẹ mọ.

Dabiri ṣalaye pe awọn alaanu ati ijọba Lebanon lo san owo ti Naijiria fi ko awọn to m bọ lalẹ yii gan an wa sile.

Ọfẹ si ni awọn ọmọ naa n de laisan kọbọ kan funra wọn.