Corona virus update in Nigeria: Ó lé ní N213 bílíọ̀nù tó wọlé fún ìjọba nípasẹ̀ COVID-19

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu
Ajọ kan to n wadi iṣuna ati inawo ijọba lorilẹede Naijiria ti kede rẹ pe owo to le ni igba o le mẹtala biliọnu naira lawọn ijọba apapọ ati ipinlẹ mẹrẹrindinlọgbọn to wa lorilẹede Naijiria ti tẹwọ gba lori ajakalẹ arun coronavirus lati fi koju arun naa.
Awọn owo naa lo wa latọwọ awọn lajọlajọ, lẹgbẹlẹgbẹ ati awọn eekan lawujọ fun ọkọọkan awọn ijọba naa eyi ti akojọpọ rẹ ti le ni igba biliọnu naira.
Pupọ lara owo naa lo wa fun ṣiṣeto amayedẹrun fun awọn araalu ṣugbọn to jẹ pe titi di asiko yii, iye ohun taraalu fi oju ri ko tii lee dọgba pẹlu owo naa.
Ninu atẹjade rẹ kan to fi sita ni ọjọ Aje, ajọ BudgIT ni awọn ipinlẹ mẹjọ pere lo tii jẹwọ ilakalẹ lori bi wọn ṣe na owo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni awọn ipinlẹ naa ni Ebonyi, Ekiti, Kaduna, Katsina, Eko, Ogun, Ondo ati Oyo.
Ninu ọrọ rẹ, ọga agba ajọ BudgIT ni o yẹ ki awọn ijọba o tubọ ko akoyawọ lori bi wọn ṣe na owo naa ki araalu lee mọ pe ọwọ wọn mọ nipa rẹ.













