Funke Oshonaike: Uwa Omozua tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ kú ní Benin ló mú mi sọ ìrírí tèmi náà

Funke Oshonaike

Oríṣun àwòrán, Facebook/Funke Oshonaike

''Ni gbogbo igba ti mo ba ti gbọ iroyin nipa ifipabanilopọ, o maa n mu mi ranti ohun to ṣẹlẹ si mi sẹyin ni. 'Wọn fipa bami lopọ, wọn si tun huwa ipa si mi, ọrọ igbe aye mi ree.''

Gbajugbaja agbabọọlu tẹniisi ori tabili to jẹ ọmọ Naijiria, Funke Oshonaike lo si aṣọ loju eegun ọrọ ri.

Orilẹede Naijiria ti bẹrẹ si ni wa ọna lati dẹkun iwa ifipabanilopọ to ti gogo bayii lawujọ, Funke wa lara awọn ilumọọka ọmọ Naijiria to n sọ iriri wọn lori ifipabanilopọ fun igba akọkọ.

Funke to ti ṣoju orilẹede Naijiria ninu idije ''Olympics'' ni igba mẹfa ọtọtọ pinnu lati sọ iriri rẹ lẹyin ti awọn kan fipa ba ọdọbinrin ọmọ ọdun mejilelogun, Uwa Omozua lopọ ti wọn si tun pa a niluu Benin.

Ihoho ni wọn ba oku Uwa ninu ile ijọsin kan ni Benin eyi to mu ki ọpọ bẹrẹ si ni ṣe iwọde kaakiri Naijiria.

Oshonaike ṣalaye pe bi wọn ti fipa ba Omozua lopọ ran ohun leti bi ọkunrin kan to fi ọdun mẹwaa ju oun lọ ṣe fipa ba oun lopọ nigba t'oun wa lọmọ ọdun mọkandinlogun.

''Ọkunrin naa da bi ọrẹ si mi, o lu mi, o si fi ika atanpako rẹ meji bọ mi loju, lẹyin naa lo fipa bami lopọ ti ẹjẹ si bo mi. Ko si ẹni to le ran mi lọwọ, mi o tiẹ mọ orukọ ti wọn n pe iru nnkan bayẹn,'' Oshonaike lo sọ bẹẹ.

Funke Oshonaike

Oríṣun àwòrán, Funke Oshonaike

Ni ọmọ ọdun mẹrinla ni Oshonaike ti bẹrẹ si ni gba tẹniisi ori tabili, lẹyin ọdun meji si igba naa ni o lọ ṣoju Naijiria ninu idije All Africa Games lọdun 1991.

Ṣugbọn Atlanta 1996 ni o ti ṣoju Naijiria ninu idije ''Olympics'' fun igba akọkọ- nigba naa gan ni ọkunrin yii bẹrẹ si ni huwa ipa si i.

Ọkunrin naa ko laya jẹ debi pe oun lo n ṣakoṣo owo rẹ ati ohun gbogbo to ni, bẹẹ si ni ko le yi ẹnu pada.

''O maa n lu mu lalubami nigba kuu gba ti o ba beere owo mi wi pe mo fẹ fi i silẹ,'' Oshonaike lo sọ bẹẹ.

Funke Oshonaike

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Funkẹ ni oun ''padanu gbogbo ohun ini oun si ọwọ ọkunrin yii ṣugbọn mo pinnu lati tẹsiwaju pẹlu gbigba tẹniisi ori tabili.''

Oshonaike sọ pe ''iriri naa ṣakoba fun igbeyawo mi, o si pami lara nipa nini ibalopọ, ṣugbọn mo ti n bori rẹ diẹdiẹ bayii.''

Funke Oshonaike

Oríṣun àwòrán, Facebook/Funke Oshinaike

Amọ Funke Oshonaike sọ pe iriri naa ko buru jai ni tootọọ ṣugbọn o ti ran oun lọwọ lati gba ọpọ obinrin ti wọn n la iru rẹ kọja niyanju.

O rọ awọn obinrin ti wọn ti ni iru iriri bayii lati sọ sita ki awọn eeyan mii le kọgbọn lara wọn.